Nitori ẹsun ifipabanilopọ, adajọ ju Damilare ati Emmanuel sẹwọn l’Ọta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Kootu Majisreeti Ọta ti paṣẹ pe ki Oluwadamilare Oyeniyi ati Emmanuel Okoji ti wọn ni wọn fipa ba ọmọ ọdun mọkandinlogun lo pọ l’Ọta, wa lẹwọn titi di ọjọ karun-un, oṣu kẹta, ọdun 2021.

Adajọ Shotunde Shotayọ ko gba ipẹ awọn mejeeji rara, niṣe lo paṣẹ pe ki wọn ṣi maa ṣe faaji lẹwọn titi digba ti igbẹjọ yoo tun waye lori wọn.

Awọn olujẹjọ meji yii ni wọn jẹwọ fawọn ọlọpaa nigba ti wọn mu wọn pe lọjọ kejila, oṣu kejila, ọdun 2020, awọn fipa wọ ọmọbinrin kan wọ yara, awọn ba a lo pọ pẹlu tulaasi, awọn si ya fidio ibalopọ naa pẹlu foonu awọn.

Wọn fi kun alaye wọn nigba naa pe ki ọmọbinrin naa ma baa le sọ feeyan lawọn ṣe ya fidio ihooho rẹ, awọn ko mọ pe yoo pada lọọ sọ fawọn ọlọpaa ni.

Ṣaaju lawọn ọmọkunrin mejeeji yii ti ba ALAROYE sọrọ ni Eleweeran, lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Abẹokuta. Alaye ti Damilare to ni Emmanuel lorukọ baba oun ṣe ni pe ọrẹbinrin oun lọmọbinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Ibukun.

O ni oṣu karun-un ree to ti ko wa sọdọ oun, tawọn jọ n gbe, bo tilẹ jẹ pe ọjọ ori rẹ ko ju mọkandinlogun lọ.

Damilare loun fẹran Ibukun pupọ, ko sohun toun ki i sọ fun un, koda, nipa ọrẹ oun ti i ṣe Emmanuel, pẹlu ọrẹbinrin iyẹn paapaa.

O ni ọrọ kan loun sọ fun Ibukun nipa Emmanuel ati ọrẹbinrin ẹ, bi Ibukun ṣe lọọ sọrọ naa fun ọrẹbinrin Emmanuel niyẹn, ohun to ṣe naa si dun oun pupọ.

Nigba ti akọroyin wa beere pe ọrọ wo lọrọ naa, Dare sọ pe bi Emmanuel ba ba ọrẹbinrin ẹ lo pọ, o maa n sọ foun, oun yoo si sọ fun Ibukun nitori oun fẹran ẹ, o ni eyi ni ọrẹbinrin oun lọọ sọ fun ti Emmanuel, niyẹn ba n binu pe ọrẹkunrin oun n yẹyẹ oun kiri.

‘‘Ọrọ naa lo ṣaa di wahala, mo waa binu si Ibukun, ṣugbọn mo tun pada fa a mọra naa ni, a dẹ bara wa sun. Ọjọ keji lo kẹru kuro nile mi, bo ṣe lọọ mu ọlọpaa wa niyẹn pe mo fipa ba oun lo pọ. O tun ni Emmanuel naa ba oun lo pọ pẹlu agidi, iyẹn o dẹ ba a sun, emi ti mo ba a ṣere gan-an ko fipa ṣe e, nitori gẹlifurẹndi mi ni’’ Bẹẹ ni Damilare, ẹni ọgbọn ọdun sọ.

Ọrọ Emmanuel naa ko fi bẹẹ yatọ, o loun ko ba Ibukun lo pọ, ọrẹbinrin oun loun n ṣe kinni fun. Njẹ bawo ni Ibukun yoo ṣe deede ti ọran mọ ọn lọrun lai ṣẹ, Emmanuel ni ko ye oun rara.

Nigba ti wọn de kootu l’Ọjọruu to kọja, nibi ti wọn ti fẹsun ifipabanilopọ ati igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi kan wọn ni wọn fẹẹ maa yi ọrọ pada, Adajọ Shotunde ko tilẹ gba ipẹ wọn rara.

O ni ki wọn ko wọn da sẹwọn, to ba di loṣu kẹta, ki wọn waa sọ tẹnu wọn.

Leave a Reply