Ibrahim Alagunmu
Ọkunrin agbẹ kan, AbdulGaniu Mohammed, ẹni ọdun mọkandilọgọta (59), ni ile-ẹjọ Magistreeti kan to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo ti sọ sẹwọn bayii fẹsun pe o fipa ba ọmọdebinrin kan lo pọ.
Agbefọba, Insipẹkitọ Zacchaeus Fọlọrunṣọ, sọ fun ile-ẹjọ pe afurasi ọdaran naa, Muhammed, lo anfaani pe ọmọbinrin to fipa ba lo pọ yii maa n tọ sile, o si n tọwọ bọ ọ loju ara pe oun fẹẹ mọ ohun to n ṣe okunfa bo ṣe maa n tọ sile, to si fi tipa-tipa ba a lo pọ. Fọlọrunsọ rọ ile-ẹjọ lati ma gba beeli rẹ.
Onidaajọ, Magistreeti Muhammad Dansuki, paṣẹ pe ki wọn sọ afurasi naa sọgba ẹwọn, o sun igbẹjọ si ọjọ kẹfa, oṣu Keje, ọdun 2022.