Nitori ẹsun ikowojẹ, awọn aṣofin Ogun ranṣẹ pe ọga OPIC tẹlẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Ẹgbẹlẹgbẹ owo ti ko ṣee foju fo, eyi ti aṣiri rẹ tu pe ọga tẹlẹ nileeṣẹ ‘Ogun State Property and Investments Corporation (OPIC), nipinlẹ Ogun, Amofin Jide Oduṣolu, ko jẹ, ni wọn ti n tori rẹ pe ọkunrin naa nile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun fun igba diẹ sẹyin. Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni wọn tun pe e wa sile naa lati ṣalaye ara ẹ nitori owo to ju miliọnu lọna ogoji lọ ni wọn ni aṣiri tun tu pe o ṣe baṣubaṣu lai ni akọsilẹ kankan.

Ẹka to n ri si ṣiṣe owo ileeṣẹ mọkumọku nile-igbimọ lo ranṣẹ pe Oduṣolu gẹgẹ bi wọn ti ṣe kọkọ pe e lọjọ kẹtala, oṣu kẹwaa, ọdun yii, to si ṣe awọn alaye ti wọn ni ko kun to, afi ko tun pada wa.

Awọn aṣofin sọ pe laarin ọdun 2015 si 2019 ti ọkunrin yii fi jẹ ọga OPIC, o ra ilẹ kan ni miliọnu lọna okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din marun-un naira (515m), o ta ilẹ naa pada ni miliọnu mẹrinlelọgọjọ(164m).

Bẹẹ, wọn ni beeyan ba fẹẹ ta ilẹ yii niye to yẹ ko jẹ, ẹgbẹrun lọna ọgọrin ati mejidinlaaadọta miliọnu ni (848m).

Yatọ si eyi, wọn ni afẹnu-na ni gbogbo owo ti ọkunrin yii na lasiko to wa nipo, akọsilẹ ẹyọ kan bayii ko si fun awọn iṣẹ to ni oun ṣe.

Bẹẹ bi wọn ba ra ohunkohun nileeṣẹ naa, o yẹ ki wọn kọ ọ silẹ kawọn ayẹwe-owo-wo (External Auditor) lati ita le waa wo o, wọn ni Oduṣolu ko ṣe tiẹ bẹẹ.

Wọn tun fẹsun miliọnu lọna ogoji to ni oun fi kọ ile kan ti wọn n pe ni Mitros, n’Ibara, l’Abẹokuta, kan an, wọn ni ko ni akọsilẹ kan.

Awọn dukia ijọba ti ọkunrin yii tun ta lasiko to ku diẹ ki ijọba Amosun to ba ṣiṣẹ kogba silẹ naa wa ninu ẹsun ti wọn fi kan an.

Gbogbo ẹsun yii atawọn mi-in ni Amofin Oduṣile sọ pe oun yoo dahun daadaa boun ba pada wa sile naa lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii. Oun funra rẹ lo mu ọjọ yii, lẹyin to ni ara oun ko ya, oun ko si ni i le pẹ pupọ nile-igbimọ lọjọ Aje, Mọnde. Wakatri meji pere lo ni oun le ba wọn lo lati dahun awọn ibẹẹrẹ naa.

O sọ fun wọn pe ki i ṣe ile-igbimọ aṣofin loun lẹtọọ lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ lasiko iṣakoso oun fun, bi ko ṣe gomina. Ṣugbọn ile naa sọ fun un un pe ko ri bẹẹ, bi Ọlọrun ba ri i, ko jẹ keeyan naa ri oun ni.

Leave a Reply