Nitori ẹsun ipaniyan, awọn akẹkọọ Fasiti Ajayi Crowther ti dero ẹwọn

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin iṣẹlẹ ibanujẹ to waye niileewe giga Fasiti Ajayi Crowther, to wa niluu Ọyọ, nibi ti awọn akẹkọọ ti lu ẹgbẹ wọn pa, mẹẹẹdọgbọn (25) ninu wọn ni wọn ti dero ẹwọn bayii lẹyin ti awọn alakooso ileewe ọhun fọwọ ara wọn fa wọn le awọn agbofinro lọwọ.

Ile-ẹjọ Majisreeti to wa niluu Ọyọ ni wọn foju aọn eeyan naa ba l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii.

Marun-un ninu awọn mẹẹẹdọgbọn (25) ti wọn fẹsun ipaniyan kan ni kootu ni: Adejumọbi Emmanuel, Daudu John Oluwaṣeun, Oloyede Fẹmi (18), Oyelakin Iyanuoluwatọmiwa, ati Afẹsọjaye Emmanuel, ti ko ju ẹni ọdun mejidinlogun (18) pere lọ; nigba ti meji ninu wọn, iyẹn Arẹyẹ Joseph Aduragbemi (19), ati Mustapha Usman Ṣẹgun, jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun (19).

Ninu wọn la ti ri awọn mẹfa ti wọn jẹ ọmọ ogun (20) ọdun. Orukọ awọn wọnyi ni Okorie Samuel, Adeniran Yusuf, Ọlalekan Ọbaloluwa, Moses Abiọla, Okay-Aroh Gerald, ati Bolarinwa Ọlọruntoyinbo Victor. Nigba ti awọn marun-un, iyẹn Kumolu Ọpẹyẹmi Daniel, Gana Solomon, Tijani Hammad, Fọlọrunshọ Oluwakunmi, ati Omon-Fumen Jenkins, jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun (21); pẹlu Kọlawọle David, to jẹ ẹni ọdun mejilelogun (22)

Orukọ awọn yooku ni Lawal Victor Tomilọla, ati Mustapha Khalid, ti wọn jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun (23); Ọmọlakin Oluwatọmiwa Anthony, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24);

Oluwole Ọlanshile Thompson, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25); . Kẹhinde Ọlaṣusuyi Martins, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32), pẹlu Ọladoye Ọladoye Fẹmi Ọla, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34).

Adajọ ko gbọ awijare awọn olujẹjọ naa to fi paṣẹ pe ki wọn lọọ ko gbogbo wọn pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn titi di ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2024 yii ti igbẹjọ ọhun yoo maa bẹrẹ gan-an ni pẹrẹu.

Tẹ o ba gbagbe, lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu Karun-un, ọdun yii, lawọn ọmọ ileewe ọhun lu akẹkọọ ẹgbẹ wọn to n jẹ Akor Alex, to jẹ ẹni ọdun mejillogun (22) pa nitori ti wọn ka foonu ọkan ninu wọn mọ ọn lọwọ nilegbee awọn akẹkọọ ti wọn n pe ni Shepherd Inn, to wa ninu ọgba fasiti naa.

Lẹyin ti wọn fi tulaasi fa gbogbo irun ori ẹ dan kodoro tan, wọn lu u to bẹẹ titi ti ko fi le ta putu mọ. Nigba naa ni wọn gbe e lọ si ẹgbẹ titi, pẹlu ireti pe o maa ji pada nigba ti atẹgun ba fẹ si i, laimọ pe akẹkọọ ọlọdun keji naa naa ti ku patapata.

Bi awọn alaṣẹ fasiti yii ṣe gbọ nípa eeyan to wa nilẹẹlẹ lẹgbẹẹ titi yii ni wọn gbe e lọ sileewosan fun itọju lati gba ẹmi rẹ la, ki awọn dokita too sọ fun wọn pe ẹni ti wọn gbe wa sọdọ awọn yii ti jade laye.

Loju-ẹṣẹ lọga agba fasiti ACU, Ọjọgbọn Timothy Abiọdun Adebayọ, ti gbe igbimọ alagbara kan kalẹ, ti oun funra rẹ si mojuto igbimọ naa lati ṣewadii lori iṣẹlẹ yii.

Lẹyin iwadii ọhun, awọn to lu oloogbe pa, awọn to n ya fidio, atawọn ti ko mọwọ, mẹsẹ, ni wọn ko, ti wọn si fa gbogbo wọn pata le awọn agbofinro lọwọ ni teṣan ọlọpaa to wa ni Durbar, niluu Ọyọ.

Awọn ọlọpaa ni wọn ṣẹṣẹ da awọn ti ko mọwọ mẹsẹ ninu ọran naa pada sileewe naa lẹyin iwadii wọn.

Leave a Reply