Nitori ẹsun jibiti, ọga agba banki rẹwọn ọdun mẹta he l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Latari bi wọn ṣe fidi ẹ mulẹ pe o jẹbi ẹsun jibiti ati fifi owo olowo ṣararindin, ẹwọn ọdun mẹta nile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko kan to fikalẹ siluu Ikẹja sọ Ọgbẹni Okey Nwosu si, oun ni ọga agba fun banki Finland nigba kan.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, Adajọ Lateefat Okunnu sọ pe ẹri to wa niwaju oun nipa ẹsun owo tiye rẹ din diẹ ni biliọnu mọkanla naira (#10.9 billion) ti wọn lo poora mọ afurasi ọdaran naa lọwọ ko ruju rara, o ni awọn alaye ti ko mọyan lori ni olujẹjọ naa n ṣe latigba ti ẹjọ rẹ ọhun ti bẹrẹ.
Yatọ si Nwosu, awọn mẹta mi-in ti ajọ to n gbogun tiwa jibiti ati ṣiṣẹ owo ilu mọkumọku, EFCC, sọ pe wọn jọọ gbimọ-pọ lati huwa buruku naa ni Dayọ Famọranti, Agnes Ebubedike ati Danjuma Okoli. Ẹsun mẹrindinlọgbọn ni wọn ka sawọn mẹrẹẹrin lẹsẹ.

Gẹgẹ bi EFCC ṣe wi, asiko tawọn mẹrẹẹrin yii fi wa ninu igbimọ alakooso banki ọhun ni wọn huwa jibiti ọhun, ki awo too ya lọdun 2012, ti igbẹjọ si bẹrẹ lọdun 2013.

Bawọn afurasi naa ṣe kọkọ sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun wọnyi lo mu ki igbẹjọ bẹrẹ ni pẹrẹwu. Ọkan-o-jọkan iwe ati akọsilẹ, pẹlu awọn ẹlẹrii si ni agbẹjọro fun EFCC  ko wa sile-ẹjọ lati fidi ododo mulẹ.

Ṣugbọn laarin kan, dipo kawọn olujẹjọ naa gbaju mọ arojare wọn lori awọn ẹsun wọnyi, niṣe lawọn naa tun gbe ẹjọ mi-in dide, wọn ni ile-ẹjọ giga naa ko lẹtọọ, ko si laṣẹ, lati gbọ ẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan awọn, wọn ni kile-ẹjọ naa jawọ lori ẹjọ ọhun.

Wọn fa ẹsun yii titi de ile-ẹjọ giga ju lọ nilẹẹ wa, idajọ to si waye lori rẹ ko ṣe wọn loore.

Igbẹjọ ẹlẹẹkeji yii ni Adajọ Okunnu ṣẹṣẹ gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ naa. O ni iwa ṣiṣi ipo lo, kiko awọn eeyan nifa, ati lilo owo tawọn kọsitọma banki naa fi sikaawọ wọn fun ete imọtara-ẹni-nikan lawọn afurasi mẹrẹẹrin naa hu.

Yatọ si Nwosu ti wọn la mẹwọn ọdun mẹta pẹlu iṣẹ aṣekara, wọn tun ran Dayọ Famọranti naa lẹwọn ọdun mẹta, oṣu mejila pere ni wọn ni ki Ocholi sare lọọ lo ni tiẹ, wọn si sọ Ebubedike si oṣu mẹfa pere.

Adajọ tun paṣẹ pe kawọn ọdaran naa padanu awọn dukia wọn to jọju kan sapo ijọba, bẹẹ ni ko saaye owo itanran fun wọn rara.

Leave a Reply