Nitori ẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara, adajọ ni kawọn ọdaran meji gbalẹ ọgba Fasiti Ilọrin foṣu mẹta

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Nitori ẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara, ile-ẹjọ giga kan to wa niluu Ilọrin ti paṣẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, pe ki awọn ọdaran meji kan; Akinọla Ọpẹyẹmi ati Owolabi Ọlajide, gba ilẹ inu ọgba ẹka ikẹkọọ Physics, ti Fasiti Ilọrin ati ileewe girama St.Anthony, fun odidi oṣu mẹta gbako.

Adajọ Sikiru Oyinloye to gbe idajọ naa kalẹ ni wọn lanfaani lati san ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ bii owo-itanran lati dipo ilẹ gbigba.

Ṣaaju lawọn mejeeji ti gba pe loootọ awọn jẹbi ẹsun tajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC, fi kan wọn.

Aṣoju ajọ EFCC, Ọgbẹni Ọlarewaju Lamidi, ṣalaye pe ninu oṣu kẹta, ọdun yii, lọwọ tẹ awọn ọdaran naa niluu Ilọrin.

O ni lasiko tawọn yẹ ori foonu iPhone ati kọmputa alaagbeka wọn wo lawọn ba oriṣiiriṣii awọn atẹranṣẹ ti wọn fi n lu jibiti.

Adajọ Oyinloye ni ẹwọn oṣu mẹfa lawọn ọdaran naa maa ṣe bi wọn ko ba gbalẹ awọn ileewe naa daadaa tabi san owo itanran. O paṣẹ fun awọn olori ẹka Physics ti Fasiti Ilọrin ati ọga agba ileewe St. Anthony lati maa yẹ ilẹ ti wọn ba gba wo, ki wọn si maa jabọ fun ile-ẹjọ.

 

Leave a Reply