Nitori ẹsun magomago, EFCC gbẹsẹ le akaunti ileegbimọ aṣofin Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu (EFCC), ti gbẹsẹ le asunwọn owo ileegbimọ awọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ.

Eyi waye latari ẹsun ti wọn fi kan wọn pe wọn ra awọn ọkọ ayọkẹlẹ kan lowo to ju iye to yẹ ko jẹ lọ.

Sẹria ti ajọ yii da fun awọn aṣofin yii ni ko jẹ ki wọn lanfaani lati le ri owo ti wọn maa n gba loṣooṣu gba lati le maa gbọ bukaata ẹkun idibo kaluku wọn.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ajọ EFCC tun gbe awọn oṣiṣẹ ileegbimọ yii kan lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii lawọn ọnarebu naa ṣi wa lahaamọ awọn agbofinro.

Leave a Reply