Nitori eto aabo lasiko ayẹyẹ ayajọ ominira, ileeṣẹ ọlọpaa ko agbofinro ẹgbẹrun kan aabọ sita ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ki eto aabo to le gbopọn le wa lọjọ ayẹyẹ ayajọ ọdun kọkanlelaaadọta Naijiria, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti ko oṣiṣẹ ẹgbẹrun kan aabọ si oju popo ni ipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni Alukoro wọn, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, ti sọ pe Ọga ọlọpaa, CP Tuesday Assayomo, ti pasẹ pe ki eto aabo to gbopọn le wa ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ti Naijiria fẹẹ ṣe ayẹyẹ ayajọ ọdun kọkanlelaaadọta ti wọn gba ominira, ki ọlọpaa ti ko din ni ẹgbẹrun kan aabọ duro ni gbogbo ojupopo, ki wọn si maa sakiyesi gbogbo irin ajeji ni tibu tooro ipinlẹ naa.

Afọlabi ni kọmisanna rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọpaa lakoko ti wọn n ba ṣe ayẹwo awọn mọto wọn loju popo, ti wọn ba si kẹẹfin irin ajeji lagbegbe wọn, ki wọn kan si agọ ọlọpaa to ba sun mọ wọn tabi ki wọn maa pe ileeṣẹ ọlọpaa si ẹrọ ibanisọrọ yii: 08125275046, 07032069501, ti wọn yoo si gbe ipe naa lẹsẹkẹṣẹ.

Leave a Reply