Nitori eto aabo to mẹhẹ, egbẹ agbaagba ilẹ Hausa ni ki Buhari kọwe fipo rẹ silẹ

Dada Ajikanje

Latari ipaniyan ati ọpọlọpọ itajẹsilẹ to n lọ kaakiri lorileede yii, paapaa ju lọ bi awọn Boko Haram ṣe bẹ awọn agbẹ to le ni aadọrin lori nipinlẹ Borno,  awọn ẹgbẹ agbaagba ilẹ Hausa ti wọn n pe ni Northern Elders’ Forum (NEF), ti gba Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, nimọran lati kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii olori orileede yii.

Oludari agba ẹgbẹ naa lori eto ipolongo ati itaniji, Dokita Hakeem Baba-Hamed, lo sọrọ naa di mimọ. O ni ohun to ti daa ju, ti yoo si buyi kun Aarẹ Buhari, ni ko fipo rẹ silẹ, niwọn igba ti apa rẹ ko ti ka eto aabo ilẹ yii mọ.

Bakan naa ni ẹgbẹ yii bu ẹnu atẹ lu Agbenusọ fun ileeṣẹ Aarẹ, Garba Sheu to sọ pe nitori pe awọn agbẹ naa ko gbasẹ lọwọ ileeṣẹ ologun ki wọn too lọ si agbegbe naa ni awọn Boko Haram pa wọn.

Ẹgbẹ yii ni ẹmi eeyan ko ja mọ nnkan kan mọ lasiko ijọba Buhari yii, beẹ ni iwa ọdaran ti waa pọ si i laarin awọn araalu. Wọn fi kun un pe awọn ko ri iṣapa kankan lati ọdọ Aarẹ ilẹ wa lati mojuto eto aabo gẹgẹ bo ṣe ṣeleri lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu nigba ti wọn n yan an sipo.

Awọn agbaagba yii sọ pe to ba jẹ ibi ti nnkan ti dara ni, ati bi wọn ṣe maa n ṣe lawọn ilu kaakiri agbaye, ko si ohun meji to yẹ ki ijọba ti ko ba le pese aabo fun awọn eeyan rẹ ṣe ju ki o kọwe fipo silẹ lọ.

Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni aọn ikọ afẹmiṣofo Boko Haram lọọ ṣeku pa awọn agbẹ to le ni aadọrin ninu oko irẹsi lasiko ti wọn n ṣiṣẹ lọwọ.

Leave a Reply