Nitori eto abo ti ko daa, awọn alaṣẹ ti ileewe Poli pa l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ileewe Gbogboniṣe Gateway, to wa ni Ṣapade, nipinlẹ Ogun, ko si ni ṣiṣi bayii, wọn ti i pa gbọingbọin ni.

Niṣe ni wọn ni kawọn akẹkọọ maa lọ sile awọn obi wọn kia, eyi ki i ṣe nitori nnkan meji, nitori eto aabo to mẹhẹ ni.

Ohun ti a gbọ ni pe niṣe lawọn alaṣẹ ileewe naa so idanwo to yẹ ki wọn ṣe kọ, wọn ni awọn akẹkọọ ki yoo ṣe e afi ti eto aabo ba nipọn si i, ti awọn si pe wọn pada.

Ole jija ati ifipabanilopọ ti wọn lo n ṣẹlẹ nileewe naa lẹnu ọjọ mẹta yii ni wọn lo n ṣẹlẹ nileewe naa, eyi lo si fa a tawọn alaṣẹ ibẹ ṣe ni kawọn akẹkọọ naa maa lọ sile wọn.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2021, ni wọn ti sọ pe kawọn akẹkọọ maa lọ sile awọn obi wọn bi iṣẹ ọjọ naa ba ti n pari, wọn lẹni ti ko ba pada sile rẹ n mọ-ọn-mọ fi ara rẹ sinu ewu ni.

Adele to n ri si igbaniwọle nileewe naa, Ọgbẹni J.O Popọla, paṣẹ fawọn akẹkọọ pe ile awọn obi ni ki kaluku wọn pada si, ki ẹnikẹni ma ṣe loun n duro nile toun n gbe gẹgẹ bii akẹkọọ, nitori bi ohunkohun ba ṣẹlẹ, ko ni ọwọ ileewe naa ninu rara o.

Awọn fijilante meji ni wọn tilẹ ni ọwọ ti tẹ lori ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe ileewe yii, wọn ni ọwọ wọn ko mọ.

Ṣugbọn Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe eto aabo ko ti i buru debi ti wọn yoo maa ti ileewe pa, ti wọn yoo maa ni kawọn akẹkọọ maa lọ sile. O ni boya o ni idi mi-in ti wọn fi ni kawọn ọmọ maa lọ sile ni.

Leave a Reply