Nitori eto idibo Satide, wọn fofin de igbekegbodo ọkọ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Ọga agba patapata fun ileesẹ ọlọpaa Naiijiria, M. A. Adamu, ti ni ko ni i si igbokegbodo ọkọ kaakiri ipinlẹ Ondo latari eto idibo sipo gomina tito yoo waye ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ ta a wa yii.

Ni ibamu pẹlu atẹjade ti Frank Mba to jẹ alukoro wọn fi sita, ofin yii lo ni o gbọdọ fẹsẹ mulẹ bẹrẹ lati aago mejila ku isẹju kan loru ọjọ Ẹti, Furaidee,  si aago mẹfa irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, to jẹ ọjọ idibo gan-an.

O ni fífi ofin de lílọ ati bibọ awọn ọkọ lọjọ idibo maa n ran awọn ẹsọ alaabo lọwọ lati tete mọ awọn onisẹ ibi, onijagidijagan atawọn to n gbero ati hu iwa ibajẹ kan tabi omiiran lasiko ti idibo ba n lọ lọwọ.

Mba ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣetan ati fi iya to tọ jẹ ẹnikẹni to ba gbìyànjú lati ja apoti ibo gba atawọn to ba fẹẹ ta tabi ra ibo lọjọ naa.

O rọ awọn araalu lati jade, ki wọn si lọọ ṣe ojuṣe wọn ní ibamu pẹlu ofin nitori pe awọn ẹsọ alaabo ti wa ni sẹpẹ lati peṣe aabo to yẹ fun wọn.

Leave a Reply