Nitori eto idibo to n bọ, Ọbasanjọ ati Mimiko ṣepade bonkẹlẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ipade bonkẹlẹ kan waye laarin aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ,  Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ati gomina Ondo tẹlẹ, Dokita Olusẹgun Mimiko, ati Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Agboọla Ajayi, lori eto idibo to n bọ lọjọ kẹwaa, oṣu to n bọ.

Lati bii ọjọ diẹ sẹyin lawọn eeyan kan ti n gbe e kiri pe o ṣee ṣe ki ẹgbẹ PDP ati ZLP fimọ ṣọkan, ki wọn si di ọkan ṣoṣo ko baa le rọrun fun wọn lati rọwọ mu ninu eto idibo naa.

Ọrọ yii tun gbilẹ si i lọsẹ to kọja yii, lẹyin ti gbajugbaja agbẹjọro kan to filu Akurẹ ṣebugbe gbe Ọnarebu Ajayi lọ sile-ẹjọ lori ọrọ iwe-ẹri to fẹẹ fi dije.

Ọpọ awọn tọrọ ọhun ka lara ni wọn n parọwa, ti wọn si n bẹ igbakeji gomina ọhun pe ko tete juwọ silẹ koun ati Jẹgẹdẹ si jọ gbero lori bi wọn yoo ṣe yẹ aga mọ Gomina Akeredolu to jẹ oludije ẹgbẹ APC nidii.

ALAROYE gbọ pe awọn gomina kan ninu ẹgbẹ PDP ni wọn lọọ bẹ Ọbasanjọ lati ba Mimiko sọrọ boya o ṣee ṣe ko gba si i lẹnu ki oun ati Agboọla le ṣatilẹyin fun Jẹgẹdẹ to jẹ oludije PDP.

Ọrọ yii ni Babatọpẹ Ọkẹowo to jẹ akọwe iroyin fun igbakeji gomina juwe gẹgẹ bii ahesọ lasan. O ṣalaye fun akọroyin wa lori foonu lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii pe ko sohun to jọ bẹẹ rara.

Ọkẹowo ni ko ṣee ṣe ki ọga ohun ṣẹṣẹ waa lọo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu kan nigba ti eto idibo ku bii ọsẹ kan pere.

Leave a Reply