Nitori fiimu ‘Ọkọ Iyabọ’ to ṣe, TAMPAN ranṣẹ pe Yọmi Fabiyi

Faith Adebọla, Eko

Yoruba bọ, wọn ni ko yẹ keeyan gbẹ koto ọta rẹ jin ju, ko maa baa si wahala fun un to ba lọọ jẹ oun funra ẹ lo ko si koto ọhun, bẹẹ lọrọ ri lasiko yii fun gbajugbaja oṣere ilẹ wa kan, Yọmi Fabiyi, pẹlu bawọn eeyan ṣe binu si i, ti wọn si n rọjo oriṣiiriṣii pẹlu ọrọ kobakungbe si i fun fiimu “Ọkọ Iyabọ” to ṣe lati fi bu Iyabọ Ojo, ṣugbọn ti ọrọ bẹyin yọ.

Ṣe lati bii ọsẹ diẹ sẹyin ni Yọmi ti n ṣiṣẹ lori fiimu naa, bo ṣe n ya a lo n po o pọ, to si n ṣeleri fawọn ololufẹ ẹ pe wọn yoo gbadun rẹ daadaa.

Ko si iṣẹ meji ti Yọmi fẹẹ ran fiimu yii ju lati bẹnu atẹ lu Iyabọ Ojo ati ọrẹ rẹ, Damilọla Adekọya, tawọn eeyan mọ si Princess, ẹsun ati ẹjọ ti Baba Ijẹṣa, iyẹn adẹrin-in poṣonu nni, Ọlanrewaju James Omiyinka, n jẹ lọwọ ni kootu ni Yọmi fi ya fiimu naa to maa jẹ kawọn eeyan mọ pe Iyabọ atawọn tiẹ kere si nọmba, pe oun lọkọ wọn, idi si niyẹn to fi pe akọle fiimu naa ni “Ọkọ Iyabọ”.

Mọnde, ọjọ Aje yii ni fiimu naa gori atẹ ayelujara, awọn ti wọn si ti n gbọ okiki ẹ tẹlẹ ko jafara lati wo o. Ṣugbọn niṣe lọrọ ti Yọmi pe lowe ni aro ninu pẹlu bawọn to wo ere naa ṣe n yọ nọfila eebu si i lara, owo aṣegbayi si di aṣekabuku mọ ọn lọwọ.

Eyi lo mu ki ẹgbẹ awọn onitiata ti wọn n pe ni TAMPAN kọwe si Yọmi, wọn ni ko waa ṣalaye bo ṣe le ṣeru fiimu bẹẹ jade lasiko yii. Ọgbẹni Yẹmi Amodu to jẹ alakooso eto iwadii, ẹtọ ati ipẹtu saawọ fun ẹgbẹ TAMPAN, sọ ninu lẹta naa pe, “A n fi lẹta yii ke si Ọgbẹni Yọmi Fabiyi to gbe fiimu ‘Ọkọ Iyabọ’ jade, lati fara han niwaju igbimọ ẹgbẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu keje, ọdun 2021.

‘‘Ọ pọn dandan lati gbe igbesẹ yii latari bi fiimu naa ṣe tun la ariwo lọ lori atẹ ayeluja, eyi ti ko ba ilana ẹgbẹ wa mu.

‘‘Yatọ siyẹn, a ti ṣakiyesi pe fimu yii tun ti fẹẹ da ikunsinu mi-in silẹ laarin ẹgbẹ TAMPAN ati araalu, eyi ko si dun mọ wa ninu rara.

‘‘A rọ ẹyin araalu ati awọn ti ọrọ yii ba kan lati mu suuru tori ẹgbẹ TAMPAN maa ṣedajọ ododo lori ọrọ yii laipẹ.’’

Koda, awọn oṣere to n sọ ede Gẹẹsi naa binu si Yọmi Fabiyi lori fiimu isọnu rẹ yii. Tonto Dikeh, gbajugbaja oṣerebinrin lede oyinbo sọ pe, “Yomi, mo mọ-ọn-mọ ma da si ọrọ ẹ lẹnu ọjọ mẹta yii ni o, ṣugbọn ohun to o ṣe yii, to jẹ pe ọrọ to n pa oloko lẹkun ni aparo tiẹ fi n ṣe ẹrin rin, o ti mi loju fun ẹ. Iwa arifin gbaa ni sawọn ti wọn ti ko si pampẹ ifipabanilopọ ri, ibaa jẹ pe wọn ti ku tabi wọn ṣi wa laaye. Ohun to daa ju eyi lọ ni mo reti lati ọdọ ẹ, Yọmi.” Bakan naa ni wọn ti sọ fiimu yii kalẹ lori ẹrọ Youtube ti wọn ti n wo o.

Yọmi naa si ti sọ fun awọn ololufẹ rẹ pe oun fi fiimu naa si ohun ti awọn eeyan le wo ni idakọnkọ lati gba alaafia laaye. O ni ni kete ti ohun gbogbo ba yanju lori rẹ, oun yoo ma kan si wọn. Bẹẹ lo ni oun ti ṣetan lati lati da ẹgbẹ awọn oṣere to pe oun lohun, ki oun si ṣalaye b’ọrọ ṣe jẹ fun wọn.

Leave a Reply