Nitori fọto ihooho obinrin kan to loun ni lọwọ, Kazeem fi jibiti gba miliọnu meje naira lọwọ rẹ n’Ijẹbu-Ode

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Beeyan ba le ewurẹ kan ogiri, yoo yiju pada si tọhun to ba ya naa ni. Iyẹn lọrọ Adetoro Kazeem tẹ ẹ n wo yii, niṣe lo bẹrẹ si i halẹ mọ obinrin kan, Gloria Ogunnupebi, pe oun yoo ju fọto ihooho rẹ to wa lọwọ oun sori ayelujara bi ko ba maa foun lowo lọ.

Nigba tiyẹn fun un de ori miliọnu meje naira lo too le lọọ sọ ohun to n ṣẹlẹ fọlọpaa, ni wọn ba lọọ gbe Kazeem nibi to farapamọ si n’Ibadan.

Gloria ṣalaye bi wahala yii ṣe bẹrẹ, o ni niṣe loun ṣadeede gba atẹjiṣẹ ti wọn fi ohun ẹnu ṣe (Voice note) lori ẹka Whatsapp oun, iyẹn ninu oṣu karun-un, ọdun yii.

O ni ẹni naa sọ pe koun fi ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000) ranṣẹ soun kia boun ko ba fẹ ki fọto ihooho oun gba ori intanẹẹti kan laipẹ.

Obinrin naa ni ẹru ba oun, ko si ma lọọ jẹ pe yoo ju fọto naa loootọ bo ṣe wi loun ṣe sare ṣe owo naa si i, oun ro pe o ti tan sibẹ ni, aṣe ẹni naa ṣẹṣẹ bẹrẹ pẹlu oun ni.

Gloria ni afi bo ṣe jẹ pe ọsẹ meji meji lẹni naa n beere owo nla lọwọ oun latigba naa, o si gba owo naa o pe miliọnu meje o tun le (7,363.900). Obinrin yii sọ pe nigba ti jibiti yii kọja agbara oun loun pinnu lati sọrọ naa fọlọpaa, oun si ti n gbe igbesẹ pe boya koun kuku pa ara oun gan-an, ki ẹni to n lu oun ni jibiti ori ayelujara yii le fi oun silẹ.

Teṣan ọlọpaa Ọbalende to wa ni n’Ijẹbu-Ode ni Gloria ti fẹjọ sun. DPO ibẹ, SP Salamu Murphy, da awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ rẹ sita lati wa ọdaran to n gbowo lọwọ obinrin yii kan, iwadii si fi han pe Kazeem Adetoro ni ẹni naa to jokoo sile rẹ l’Ojule keji, Opopona Paara, Alaakia, n’Ibadan, to n fowo ṣara rindin latọdọ Gloria.

Bi wọn ṣe mu un lo jẹwọ pe loootọ ni, oun lẹni naa to ti n gbowo lọwọ Gloria Ogunnupebi. O loun ni akanti to pọ lẹka OPAY, ohun toun fi n gbowo lọwọ awọn to ba ko soun lọwọ niyẹn.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi,Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, sọ pe ọga awọn ti paṣẹ pe kawọn wadii Kazeem Adetoro yii daadaa lati mọ awọn iṣẹ ibi to ti ṣe sẹyin, kawọn si gbe e lọ si kootu laipẹ rara.

Leave a Reply