Nitori fuufu, Lekan gun ẹgbọn rẹ lọbẹ pa ni Mọdakẹkẹ

Florence Babaṣọla

Titi di bi a ṣe n kọroyin yii, wọn ko ti i gburoo ọmọdekunrin ẹni ọdun mejidinlogun kan, Lekan Ọdẹtayọ, ẹni ti wọn lo gun ẹgbọn rẹ lọbẹ pa ni Mọdakẹkẹ, nipinlẹ Ọṣun.

Adugbo Ifẹdapọ, niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lopin ọsẹ to kọja, gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ. Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ni Toheeb, ẹni ọdun mọkanlelogun, to jẹ ẹgbọn Lekan sọ pe ko lọọ ba oun ra fuufu wa, ṣugbọn ti Lekan sọ pe oun ko le lọ.

Ọrọ yii la gbọ pe o da ija silẹ laarin wọn, ti wọn si na ara wọn nibẹ, awọn obi wọn pẹlu awọn ti wọn jọ n gbe ni wọn mu wọn, ti wọn si pari ija ọhun, ṣugbọn wọn ni Lekan sọ pe oun maa jọ ẹgbọn oun loju fun nnkan to ṣe foun.

A gbọ pe Lekan wọnu ile, jijade to si n jade bọ, ṣe lo fi kinni kan gun ẹgbọn rẹ lọrun lai jẹ ki iyẹn fura rara, ariwo irora ti Toheeb ke lo jẹ kawọn eeyan sun mọ ibi to wa, nigba ti wọn maa ri i, ọbẹ ni Lekan fi gun un lọrun, loju-ẹsẹ naa lo si ku.

Kia la gbọ pe Lekan na papa bora, ko si si ẹni to gburoo rẹ lati alẹ ọjọ naa.  Baba wọn, Muritala Kazeem Ọdẹtayọ, lo lọọ fi iṣẹlẹ naa to ọlọpaa leti laaarọ ọjọ keji, ti wọn si gbe oku Toheeb lọ sile igbokuu-si ti ileewosan OAUTHC, Ileefẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, o ni awọn ọlọpaa ti n ṣakitiyan lati wa Lekan ri nibikibi to ba wa, ko le waa sọ nnkan to ri lọbẹ to fi waro ọwọ.

Ọpalọla ṣalaye pe nigba tawọn ọlọpaa ṣabẹwo sile awọn Lekan, wọn ba ọbẹ kan ti ẹjẹ wa lara rẹ lọgangan ibi ti Toheeb ṣubu si, wọn si ti mu u sọdọ.

Leave a Reply