Nitori gbese, Baba alajọ pokunso ni Kwara

Ọkunrin alajọ kan, Habibullahi Aminullahi, ti binu pokunso niluu Ganmọ, nipinlẹ Kwara, nitori gbese ẹgbẹrun lọna igba naira ti wọn ṣẹ si i lọrun.

Ajọ ni wọn sọ pebaba naa maa n gba ninu ilu ọhun, bẹẹ lo tun ni awọn ẹrọ to fi n lọ ata, elubọ atawọn nnkan mi-in.

Ninu ṣọọbu ẹ to wa lojuna Ajaṣẹ-Ipo, ni Kwara, ni aburo ẹ kan ti ri i nibi to pokunso si. Ko too para ẹ yii ni wọn lo ti kọkọ sọ fawọn eeyan ẹ pe oun jẹ gbese ẹgbẹrun lọna igba naira (N200,000). Ẹnikan to sun mọ ọn daadaa to ba awọn oniroyin sọrọ ṣalaye pe, suuru lawọn fun un lọjọ naa, tawọn si ba a sọrọ pe nnkan yoo yipada si rere fun un laipẹ.

ALARỌYE gbọ pe ẹrọ ilọta marun-un lọkunrin yii ni laarin ilu naa, bẹẹ lo ni ile meji, to tun ni mọto kekere kan to fi n ṣe taksi. Ọrẹ ẹ to ba awọn oniroyin sọrọ yii sọ pe iyalẹnu lọrọ ẹ ṣi n jẹ, nitori pe o ni awọn dukia to le ta, dipo bo ṣe pa ara ẹ danu yii. Bakan naa la gbọ pe ọkunrin naa ṣẹṣẹ fẹ iyawo keji ni, tiyẹn si wa ninu oyun bayii.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, SP Ajayi Okesanmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni loootọ niṣẹlẹ ọhun waye, ṣugbọn ọkunrin naa ko kọ iwe kankan silẹ lati ṣalaye ohun to mu un pokunso.

Leave a Reply