Nitori gilaasi, obinrin yii gun aburo ọkọ ẹ lọbẹ pa l’Agbado

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Ọrọ ti ko to nnkan lo gbe obinrin yii, Cynthia Olukiowu, ẹni ọgbọn ọdun, de ẹka to n gbọ ẹjọ ipaniyan nipinlẹ Ogun bayii. Niṣe lo fi ọbẹ gun ọmọkunrin ẹni ọdun mejidinlogun to jẹ aburo ọkọ ẹ, to si n gbe pẹlu wọn, lọbẹ lọrun lọjọ Satide to kọja yii, ọmọ naa si ṣe bẹẹ dero ọrun.

Ojule keji, Opopona Apogidonoyo, Jafa, l’Agbado, nipinlẹ Ogun ni obinrin yii n gbe pẹlu ọkọ ẹ ati ọmọkunrin ti wọn porukọ ẹ ni Habeeb Arẹmu yii.

Afi bo ṣe di ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un, oṣu kẹfa, ọdun 2022 yii, ti ohun ti ko to nnkan pada di ohun to n mu ẹmi lọ.

Gẹgẹ bawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe wi, gilaasi kan ti wọn fi n woju ninu ile awọn Cynthia lo fọ lọjọ naa, wọn si ni Habeeb to jẹ aburo ọkọ rẹ yii lo fọ ọ.

Gilaasi to fọ yii bi Cynthia ninu ju, ọrọ naa si di ohun ti oun ati Habeeb n tahun sira wọn le lori, to di pe wọn woju ara wọn gidi.

Lasiko ija naa ni wọn ni Cynthia fa ọbẹ yọ,  n lo ba fi gun aburo ọkọ to lo fọ gilaasi lọrun, n lẹjẹ ba bo ọmọkunrin naa.

Wọn sare gbe e lọ sọsibitu loootọ, ṣugbọn oro ọbẹ naa lo pada gba ẹmi Habeeb, ẹni to ti padanu ẹjẹ rẹpẹtẹ.

Eyi niṣẹlẹ naa fi dohun tawọn ọlọpaa gbọ, ti wọn fi lọọ mu Cynthia, ti wọn ju u sẹyin gbaga ni teṣan ọlọpaa Agbado. Mọṣuari ọsibitu Jẹnẹra Ifọ ni wọn gbe oku Habeeb si.

CP Lanre Bankọle, ọga ọlọpaa Ogun, paṣẹ pe ki wọn gbe iyawo oninufufu naa lọ sọdọ awọn to n gbọ ẹsun ipaniyan, nibi ti wọn yoo ti wadii lẹnu rẹ daadaa, ti wọn yoo si gbe e lọ si kootu fun ijẹjọ ẹsun ipaniyan.

Leave a Reply