‘‘Ki i ṣe pe mo fẹẹ pa a, mo nifẹẹ rẹ pupọ, o si wu mi lati fẹ ẹ sile bii iyawo mi ni. Ṣugbọn iṣẹ aṣẹwo to n ṣe ti mo ni ko fi silẹ ti ko gbọ lo n dun mi, mo kan fẹẹ fi gilaasi to gun un pa yẹn dẹru ba a ni, mi o mọ pe o maa ku’’
Ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan torukọ ẹ n jẹ Ikechukwu Micheal, lo sọrọ yii fawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, nigba ti wọn mu un fun iku ololufẹ ẹ, Chinyere Oji; ẹni ti wọn lo gun pa nile wọn to wa ni Ojule kọkanla, Opopona Abuja, Alaba Rago, l’Ekoo.
Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹta yii, ni wahala ṣẹlẹ, gẹgẹ bi Ikechukwu funra ẹ ṣe sọ. O ni niṣẹ ni Chinyere ko fẹẹ ṣilẹkun foun lalẹ ọjọ naa, bẹẹ ọdun kẹta ati oṣu mẹrin ree tawọn ti jọ n gbele bii tọkọ-tiyawo, lẹyin toun pade ẹ nibi iṣẹ aṣẹwo to n ṣe l’Apapa.
O ni bawọn ṣe jọ n gbe yii naa ni ọmọbinrin ẹni ọdun mejidinlogoji (38) naa ṣi maa n jade lalẹ, ti yoo lọọ ṣiṣẹ aṣẹwọ. Ikechukwu sọ pe oun ko tori ẹ da a laamu, nitori oun nifẹẹ rẹ, o mere i ṣe lori bẹẹdi, o si tun n mu siga ati ọti bii oun paapaa ni.
O ni ṣugbọn nigba toun ti lero lati fẹ ẹ loun ko ti fẹ ko ṣe iṣẹ aṣẹwo naa mọ, ṣugbọn Chinyere ko fẹẹ gba, o ṣaa n jade lalẹ o n gbeṣẹ lọ ni.
Bo ṣe tun fẹẹ lọ lalẹ ọjọ naa toun ko fẹẹ gba fun un ni Ikechukwu sọ pe o fa wahala, nitori oun tilẹkun mọ ọn pe ko ni i jade.
Lati tubọ dẹru ba a lo ni oun ṣe gbe gilaasi tawọn n wo ninu yara naa, oun la a mọlẹ, bo ṣe fọ niyẹn, to si wọ Chinyere lẹgbẹẹ, lo wa n pariwo pe kawọn eeyan waa gba oun, nitori oun ti gun oun nigo pa.
Ṣugbọn awọn eeyan sọ pe ki i ṣe pe gilaasi wọ Chinyere lẹgbẹẹ lasan, wọn ni Ikechukwu lo fi gun un, nitori oun ti ọbirin naa n wi bo ṣe n jẹrora niyẹn ko too pada ku.
Ọmọ meji ni Chinyere ti bi ko too pade Ikechukwu, obinrin to jẹ akọbi jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun, iyẹn naa ti bimọ kan nile ọkọ. Ọmọ ọdun mẹsan-an lọmọ Oloogbe Chinyere keji, ọkunrin loun.
Ṣaa, wọn ti gbe Ikechukwu ju sahaamọ, awọn ọlọpaa ni yoo de kootu laipẹ.