Nitori iṣẹlẹ idigunjale to n waye lemọlemọ, Ọọni paṣẹ iṣede niluu Ileefẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, ti paṣẹ iṣede laarin ilu naa lati aago mọkanla alẹ si aago marun-un aarọ latari iṣẹlẹ idigunjale to n waye lemọlemọ nibẹ.

Nigba to n fidi ikede naa mulẹ, Lọwa Adimula Ifẹ, Oloye Agba Abraham Adekọla, ẹni to wa ni ipo kẹta si Ọọni ṣalaye pe igbimọ Ọọni-in-Council tete gbe igbesẹ naa lati fopin si iwa ipa niluu naa.

Oloye Adekọla sọ pe ilu Sokoto ni Ọba Ogunwusi wa,nibi iṣẹ pataki kan to lọ fun, nigba ti iṣẹlẹ idigunjale fi bẹrẹ si i di lemọlemọ bii ẹkun apọkọjẹ, idi si niyẹn tawọn oloye aafin fi gbe igbesẹ ọhun.

O sọ siwaju pe awọn adigunjale ọhun ti gbajọba niluu Ileefẹ, bi wọn ṣe n pa awọn eeyan ni wọn n daamu ọpọlọpọ, ko si si ẹni to loju oorun mọ.

O fi da awọn araalu loju pe ko sẹnikankan ti yoo fiya jẹ ẹnikẹni lasiko iṣede naa, ati pe fun anfaani gbogbo eeyan ni igbesẹ naa wa fun.

Lasiko iṣede ọhun, Oloye Adekọla sọ pe ko ni i si aaye fun ariya alẹ, iṣọ-oru ati irinkerindo lalẹ titi ti gbogbo nnkan yoo fi pada si bo ṣe wa tẹlẹ.

O tun sọ siwaju pe awọn ọlọpaa, fijilante atawọn oloye ilu ko sun, bẹẹ ni wọn ko wo lori ọrọ naa.

Leave a Reply