Nitori ibalopọ, ale da ororo gbigbona si baale ile lara

Njẹ ẹyin gbọ nipa iṣẹlẹ kan to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii? Ọmọge kan lo diidi gbe ororo kana, to jẹ ko gbona daadaa, to si da a  si baale ile ti wọn jọ n yan ara wọn lọrẹẹ lara, ni gbogbo ẹyin ọkunrin naa ba bo torotoro l’Abuja ti wọn jọ n gbe.

Fidio iṣẹlẹ naa gori ayelujara gudẹ ni, n lawọn eeyan to wa nibẹ ba n lu ọmọbinrin pupa naa, wọn n sọ pe ko ma fi oju pamọ o, ko jẹ kawọn eeyan ri oju ẹ kedere ni.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an ni pe ọkunrin to da ororo gbigbona lu lara yii ki i ṣe apọn, iyawo atawọn ọmọ rẹ wa niluu Eko, iṣẹ lo gbe oun wa si Abuja.

Abuja naa lo ti pade ọmọbinrin ti wọn jọ n yan ara wọn lọrẹẹ yii, ọmọbinrin naa ko lọkọ ni tiẹ, oun ati ọkunrin to sanra daadaa naa jọ n gbe nnkan sinu ara wọn ni.

Ọkunrin naa lo pe ọmọge rẹ yii pe ko waa ba oun ṣere, iyẹn si lọ. Ṣugbọn boya ọmọbinrin naa ko fẹ ko ba oun lo pọ ni, baale ile naa ko si fẹẹ gbọ iru ẹ seti, n lo ba fipa ṣe kinni fọmọbinrin naa, lo ba gba ileewẹ lọ lẹyin ti ṣetan.

Asiko to n wẹ lọwọ lọmọge gbe ororo kana, bo ṣe n jade bọ lati ileewẹ, to kọ ẹyin si ololufẹ rẹ yii ni ọmọge da ororo to gbona si i lẹyin, niṣe lẹyin naa si bo torotoro, to pọn rokoṣo.

Ohun to ṣẹlẹ naa ko ṣee dakẹ si, ọkunrin yii ko le duro, o jade sita, awọn araale si ri i, ni wọn ba ni ọmọbinrin ọhun ni lọwọ ju.

Wọn ni igba akọkọ kọ ree ti yoo gbiyanju lati ṣe ọrẹkunrin ẹ yii nijamba, wọn lo ti fẹẹ pa a ri to jẹ ori lo ko o yọ.  Ṣugbọn nitori ọkunrin naa nifẹẹ rẹ lo ṣe tun pe e pada, ti wọn tun jọ n ba ere aniyan lọ.

Ninu alaye ẹ to ṣe, ọmọbinrin yii sọ pe ọkunrin naa ti fẹran ko maa fipa ba oun lo pọ ju boun ba ti wa a lọ. O ni ohun to jẹ koun da sẹria fun un niyẹn.

Leave a Reply