Nitori ibalopọ ati jibiti, wọn le olukọ ati oṣiṣẹ fasiti mẹtala danu

Faith Adebọla

Awọn alakooso Fasiti Ambrose Ali (AAU), to wa nipinlẹ Edo, ti kede pe lẹyin iwadii to muna doko tawọn ṣe, ati ọpọ ẹri to wa niwaju awọn, igbimọ alaṣẹ fasiti naa ti paṣẹ yiyọ olukọ ati oṣiṣẹ mẹtala kan danu bii ẹni yọ jiga nileewe ọhun. Wọn ni eyi ti wọn ṣe to, wọn ki i ṣe olukọ awọn mọ, ki wọn wa iṣẹ wọn siwaju.

Eyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe ni wọn jẹbi ẹsun iwa ainitiju, bii ki wọn maa dunkooko mọ awọn akẹkọọ-binrin pe ti wọn ko ba fẹyin lelẹ fawọn, awọn ko ni i jẹ ki wọn paasi ẹkọ ti wọn n kọ. Bẹẹ lawọn kan ninu wọn si gba owo-ẹyin lọwọ awọn akẹkọọ kan, ti ẹri si fidi rẹ mulẹ daadaa.

Ni ti awọn ti ki i ṣe olukọ lara wọn, to jẹ oṣiṣẹ inu ọgba fasiti ni wọn, lara awọn ẹsun tawọn jẹbi rẹ ni iwa yiyiwee, wọn lawọn kan yi ọjọ-ori, awọn mi-in si lu jibiti, ati awọn aṣemaṣe gbogbo to ta ko ofin ileewe giga ọhun.

Ọga agba fasiti naa, Ọjọgbọn Asomwan Sunny Adagbọnyin, sọrọ yii di mimọ lọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un yii, lasiko to n jabọ iwadii awọn igbimọ to yiri ẹsun ti wọn fi kan awọn arufin naa wo. O ni awọn alaṣẹ dori ipinnu lati gbaṣẹ lọwọ gbogbo awọn arufin tọrọ kan yii latari bi igbimọ onibaawi ṣe fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni wọn jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn, wọn lawọn kan ninu wọn tiẹ fẹnu ara wọn jẹwọ, ti wọn si rawọ ẹbẹ pe ki wọn jeburẹ lori ọrọ awọn.

Ọga agba naa ni, yatọ si pe awọn kọwe, ‘iṣẹ rẹ ti tan pẹlu wa o’ fawọn eeyan yii, o lawọn kan lara wọn ṣi maa lọọ rojọ ẹnu wọn fawọn agbofinro, tori awọn ti mu ẹjọ wọn lọ sọdọ wọn, ati pe ẹṣẹ tawọn eleyii ṣẹ kọja ọrọ irufin ṣakala, ọrọ tiwọn lọwọ kan iwa ọdaran ninu.

O ni ọjọgbọn kan, iyẹn purofẹsọ, ati olukọ kan, wa lara awọn tawọn le bii ẹni le aja, tori iwa aitọ patapata gbaa ni wọn hu.

O tun sọ pe olori ẹka ti wọn ti n gba imọ iṣẹ nọọsi nileewe naa wa lara awọn ti wọn le danu, owo abẹtẹlẹ laṣiiri tu pe wọn gba lọwọ awọn akẹkọọ wọn. Awọn kan san ẹgbẹrun mejilelọgbọn (N32,000), awọn mi-in si san ẹgbẹrun mejilelaaadọta (N52,000) fọgaa ọhun.

Ọjọgbọn Adagbonyin pari ọrọ rẹ pe ninu iwe ẹsun igba ati mẹsan-an tawọn ṣiṣẹ le lori, awọn ti fẹnu ọrọ jona lori mejilelaaadoje, iwadii ati igbẹjọ ṣi n lọ lori mẹtadinlọgọrin to ku, lojuna ati fọ ileewe ọhun mọ, kawọn si yọ gbogbo kan-n-da inu irẹsi to n huwa idọti ati irufin ninu ọgba fasiti naa.

Leave a Reply