Nitori ibẹru awọn akẹkọọ, Fasiti Imọ Iṣegun Ondo ti ileewe pa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lati dena ifehonu han tawọn akẹkọọ n gbero lati ṣe ta ko owo ileewe wọn tijọba ṣẹṣẹ ṣe afikun rẹ ni ilọpo lọna ilọpo, awọn alaṣẹ Fasiti Imọ Iṣegun oyinbo to wa loju ọna Laje, niluu Ondo, ti pasẹ fun gbogbo awọn akẹkọọ ileewe ọhun lati tete gba ile obi koowa wọn lọ lẹyẹ-o-ṣọka.

Ninu atẹjade kan tawọn alaṣẹ fasiti naa fi sita, eyi ti Ezekiel Adeniran fọwọ si lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo ti fun awọn oṣiṣẹ atawọn akẹkọọ ni gbedeke wakati mejidinlaaadọta pere (ọjọ meji) lati fi ko gbogbo ẹru wọn kuro ninu ọgba ati sakaani ileewe naa.

Wọn ní kawọn akẹkọọ ti wọn ṣẹṣẹ n wọle fun saa tuntun 2021/2022 tete maa pada sile wọn nitori pe awọn alaṣẹ ti sun ọjọ iwọle siwaju di ọjọ mi-in ọjọ ire.

Akẹkọọ to ba kọ ti ko tẹle aṣẹ ti wọn pa ni wọn ni ko maa reti ijiya to tọ sọmọ alaigbọran.

Lati ọsẹ to kọja tijọba ti gbe owo tawọn akẹkọọ naa n san kuro ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira le diẹ to wa tẹlẹ lọ si miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna oji lenirinwo le marun-un Naira lara ko ti rọ okun ti ko si rọ adìẹ ni fasiti ọhun mọ.

Ohun to n kọ awọn obi atawọn akẹkọọ lominu lori ọrọ yii ni bi Gomina Rotimi Akeredolu ṣe fi wọn gun lagidi, ti ijọba rẹ ko tii sọ ohunkohun nipa rẹ ni gbogbo asiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.

 

 

 

Leave a Reply