Nitori ibẹru korona, ijọba ni ki gbogbo ileewe bẹrẹ isinmi l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede pe ki gbogbo awọn ileewe ijọba ati ti aladaani bẹrẹ ọlude Keresimesi lọla.

Ninu atẹjade kan ti Alakooso feto ẹkọ, C K Ọlaniyan, fi sita lo ti ṣalaye pe ọrọ eto aabo ẹmi ati dukia awọn araalu jẹ ijọba logun pupọ.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun yii, lo yẹ ki awọn ileewe kaakiri ipinlẹ naa gbọlude, ṣugbọn pẹlu wahala ajakalẹ arun koronafairọọsi ti iye awọn to ti ni i tun ti n pọ si i, lo jẹ kijọba gbe igbesẹ naa ni kiakia.

Ọlaniyan sọ pe ijọba yoo kede ọjọ ti awọn ileewe yoo wọle fun eto ẹkọ lọdun tuntun ni kete ti aridaju ba ti wa pe aabo to peye wa fun awọn ọmọleewe naa.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Igbẹjọ Timothy Adegoke: Adedoyin ṣepe fawọn oniroyin ni kootu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo Iyalẹnu lo jẹ fawọn oniroyin laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, yii, nigba ti Dokita …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: