Nitori ibo 2023, awọn ọmọ Tinubu kọju ija si Fayẹmi

Oluyinka Soyemi

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) tipinlẹ Ekiti ko da bii ti tẹlẹ mọ nitori nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa lọwọlọwọ fi han pe igun meji lo wa, ko si jọ pe ẹni kan fẹẹ gba fun ẹni keji, bo tilẹ jẹ pe ariwo ija lọọlẹ diẹ.

Igun akọkọ jẹ ti Oludamọran pataki lori ọrọ oṣelu fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Sẹnetọ Babafẹmi Ojudu, pẹlu ọkọ ọmọ Aṣiwaju Ahmed Tinubu, Ọnarebu Olubunmi Ojo, atawọn eeyan bii Dokita Wọle Oluyẹde, Ẹnjinnia Ayọ Ajibade, Ọnarebu Fẹmi Adelẹyẹ, Bunmi Ogunlẹyẹ, Akin Akọmọlafẹ, Bamigboye Adegoroye, Oluṣọga Owoẹyẹ, Dele Afọlabi ati Toyin Oluwaṣọla.

Igun yii naa tun ni Sẹnetọ Tony Adeniyi, Sẹnetọ Dayọ Adeyẹye, Ọnarebu Bimbọ Daramọla, Ọnarebu Robinson Ajiboye, Ọnarebu Adewale Omirin ati Ọnarebu Fẹmi Adelẹyẹ wa.

Sẹnetọ Babafẹmi Ojudu

Gomina Kayọde Fayẹmi wa ni igun keji pẹlu awọn aṣofin to wa lori aleefa lọwọlọwọ nipinlẹ naa ati l’Abuja, bẹẹ lawọn oloṣelu nla nla mi-in wa lọdọ wọn, eyi to fi mọ igbimọ adari ẹgbẹ naa l’Ekiti ti Amofin Paul Ọmọtoshọ jẹ alaga fun.

Ki i ṣe ọdun yii ni Ojudu ati Fayẹmi ti n ba ija naa bọ, ṣaaju oṣu karun-un, ọdun 2018, ti ibo abẹle APC waye lati yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa nibi ibo gomina ni Ojudu ti n sọ pe Fayẹmi ko le ṣe daadaa fun ẹgbẹ naa, eyi lo si jẹ ko yọ ara ẹ kuro ninu awọn to n dije nibi ibo abẹle ọhun.

Nigba to di nnkan bii oṣu kẹfa, ọdun yii, ija kan ṣẹlẹ pẹlu bi Ojudu ṣe ni Fayẹmi sọ fawọn ọmọọṣẹ ẹ kan lati da diẹ ninu apo irẹsi toun pin fawọn eeyan kaakiri ipinlẹ naa pada lẹyin bii oṣu mẹta toun ti pin in, eyi si waye nigba to ni kawọn adari wọọdu fun oun niwee gbele-ẹ tawọn yẹn ko da a lohun. O ni eyi fi han pe Fayẹmi n lo gbogbo agbara lati wahala oun.

Ọmọọba Dayọ Adeyẹye

Ọrọ ile-ẹjọ ti Ojudu atawọn eeyan ẹ gba lọ lo da bii ẹni pe o mu ija naa burẹkẹ, iyẹn lẹyin ti wọn ni igbimọ alaṣẹ ipinlẹ naa ti Amofin Paul Ọmọtọshọ n dari ko ba ofin mu. Wọn ni Fayẹmi kan ko awọn kan lọ si kọrọ ti wọn yan awọn eeyan ọhun ni, ko si ibo ẹgbẹ ni wọọdu ati tijọba ibilẹ gẹgẹ bi ofin ṣe sọ.

Bayii ni ọrọ naa ṣe n lọ, ti oriṣiiriṣii iroyin si n jade pẹlu bi awọn alatilẹyin Ojudu ṣe n sọrọ, tawọn ti Fayẹmi naa n da wọn lohun.

Ni bii ọsẹ mẹta sẹyin ni adari ẹka iroyin ẹgbẹ naa l’Ekiti, Sam Oluwalana, kede pe awọn fẹẹ gbe igbesẹ kan lori aṣẹ tawọn adari ẹgbẹ lapapọ pa pe kawọn ọmọ ẹgbẹ fopin si gbogbo ẹjọ ni kootu, ṣugbọn tawọn ọmọ ẹgbẹ kan ko tẹle.

O ni nitori eyi, awọn ti gbe igbimọ oluwadii kan kalẹ lati ṣeto bi iwe gbele-ẹ yoo ṣe tẹ awọn mejila kan lọwọ, iyẹn awọn ti wọn n ba ẹgbẹ ṣejọ ni kootu, bo tilẹ jẹ pe wọn yoo lanfaani lati ṣalaye ara wọn.

Eyi ni awọn Ojudu fesi si pe ọrọ yẹyẹ ni, nitori ko si ootọ kankan ti yoo ti ibẹ jade, ati pe otẹẹli Ọmọtọshọ to wa lara awọn tawọn pe lẹjọ ni wọn ti fẹẹ jokoo sọrọ, bẹẹ ni Oluwalana tiẹ ti sọ iṣẹ ti wọn ran igbimọ ọhun.

Nigba to di ọsẹ to kọja, Ọnarebu Ade Ajayi to jẹ agbẹnusọ APC l’Ekiti kede pe awọn ti fun Ojudu atawọn mẹwaa mi-in ti wọn wa ni igun ẹ niwee gbele-ẹ lẹyin abajade igbimọ tawọn gbe kalẹ, ṣugbọn wọn yọ ẹni kejila, iyẹn Ben Oguntuaṣe, ẹni ti wọn lo ti sọ pe oun ko si ninu igun naa.

Ṣugbọn igun keji fesi pe igbesẹ naa ko lẹsẹ nilẹ nitori awọn alaṣẹ ti wọn yan labẹ ofin lo le gbe iru igbesẹ bẹẹ, ati pe wọọdu ni wọn tiẹ ti n fun ọmọ ẹgbẹ niwee gbele-ẹ, ki i ṣe sẹkiteriati ipinlẹ.

Lẹyin wakati diẹ ti APC gbe igbesẹ naa lawọn Ojudu ko ara wọn jọ lati gbe ipinnu kalẹ, awọn mẹjọ lo si fọwọ si ipinnu ọhun. Awọn eeyan naa ni Ojudu funra ẹ, Sẹnetọ Tony Adeniyi, Sẹnetọ Dayọ Adeyẹye, Ọnarebu Oyetunde Ojo, Ọnarebu Bimbọ Daramọla, Ọnarebu Robinson Ajiboye, Ọnarebu Adewale Omirin ati Ọnarebu Fẹmi Adelẹyẹ.

Wọn ni awọn ti woye pẹlu ẹri pe Fayẹmi ko pe ipade ẹgbẹ kankan ri lari oṣu kẹwaa, ọdun 2018, to ti di gomina, bẹẹ ni igbimọ alaṣẹ ipinlẹ ko ni aṣẹ ajọ eleto idibo (INEC) gẹgẹ bi ofin ṣe sọ, nitori naa, wọn kan di ipo ti ko tọ si wọn mu ni.

Wọn ni Fayẹmi gba Fẹmi Fani-Kayọde to jẹ ọmọ ẹgbẹ alatako (PDP) lalejo nile ijọba lati ta APC ni gbanjo, ko si pẹ ti ọkunrin naa kuro l’Ekiti to fi sọko ọrọ si Aṣiwaju Ahmed Tinubu gẹgẹ bo ṣe maa n bu Aarẹ Muhammadu Buari ati Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo ni gbogbo igba.

Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu

Igbesẹ yii ni wọn ni Fayẹmi gbe nigba to ku ọjọ diẹ ki ibo Edo waye, ninu eyi ti APC ti pada fidi-rẹmi, ti ẹri si wa pe awọn eeyan dunnu nile ijọba Ekiti lẹyin abajade ọhun.

Wọn ni Fayẹmi tun ṣatilẹyin fun Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ lati jawe olubori, bẹẹ ọmọ ẹgbẹ alatako ni.

Bakan naa ni wọn ni Fayẹmi mọ-ọn-mọ jẹ ki Dayọ Adeyẹye fidi-rẹmi nile-ẹjọ ti ipo sẹnetọ to wa si bọ sọwọ alatako, Sẹnetọ Biọdun Olujimi, lẹyin ibo ọdun to kọja.

Wọn waa ni gomina naa n ṣiṣẹ pẹlu PDP nitori ti ipo aarẹ to fẹẹ du labẹ APC ba fori ṣanpọn, yoo lọọ ṣe igbakeji aarẹ labẹ PDP.

Nitori idi eyi, wọn ni awọn ti gbe igbimọ alaṣẹ tuntun kalẹ l’Ekiti nilana ofin, eyi ti Sẹnetọ Tony Adeniyi jẹ alaga fun, awọn si ti fẹnu ko lati fun Fayẹmi niwee gbele-ẹ, bẹẹ ni igbimọ Ọmọtoṣhọ ko gbọdọ pe ara ẹ ni ojulowo mọ.

Fayẹmi fẹsi si igbesẹ yii nipasẹ adari ẹka iroyin ẹ, Yinka Oyebọde, o ni oniyẹyẹ lawọn Ojudu, ayederu si ni wọn ni gbogbo ọna. O waa ni oun ni adari ẹgbẹ naa l’Ekiti, ko si si nnkan to le yẹ ẹ.

Kia ni awọn adari ẹgbẹ naa lapapọ gbe atẹjade kan sita, ninu eyi ti wọn ti ni ko si ọrọ gbele-ẹ kankan ninu ẹgbẹ APC l’Ekiti, ọmọ ẹgbẹ ni Ojudu ati Fayẹmi. Wọn ni Fayẹmi ni adari ẹgbẹ, Ọmọtọshọ ni alaga, ko ju bẹẹ lọ, ki onikaluku sinmi agbaja.

Iwadii ALAROYE fi han pe ko sẹni to mọ pe ọrọ naa yoo lagbara to eleyii, nigba to si ti ri bẹẹ, awọn tọrọ kan ti n woye ohun ti yoo tun ṣẹlẹ, ṣugbọn ko sẹni to fẹẹ sọ nnkan kan nipa rẹ mọ lasiko yii ju nnkan ti wọn ti sọ tẹlẹ lọ.

Ọkan ninu awọn adari ẹgbẹ naa ta a forukọ bo laṣiiri sọ pe awọn iṣẹlẹ to ba ni lẹru lo waye laarin ọsẹ mẹta ninu ẹgbẹ naa l’Ekiti, ko sẹni to mọ pe ibi ti yoo ja si niyi, ṣugbọn awọn adari ti n ṣiṣẹ labẹnu, gbogbo awọn tọrọ si kan ni wọn yoo pe lati pari ọrọ ọhun nitubi-inubi nitori o le ṣakoba fun APC ninu ibo ipinlẹ lọdun 2022 ati tijọba apapọ lọdun 2023.

Leave a Reply