Nitori ibo gomina to n bọ l’Ondo, Ọlanusi pada sọdọ Mimiko

Iyiade Oluṣẹyẹ, Akurẹ

Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ, Alli Ọlanusi, ti pada sọdọ ọga rẹ tẹlẹ, Oluṣẹgun Mimiko, to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ naa.

Ọsẹ to kọja ni ọkunrin naa pari ija pẹlu Dokita Olusẹgun Mimiko, lẹyin ọdun marun-un ti wọn ti n ja. Eyi ko sẹyin eto idibo to fẹẹ waye lọjọ kẹwaa, osu kẹwaa, ọdun ta a wa yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, Alaaji Ọlanusi pinnu ati kuro ninu ẹgbẹ APC latari bi aayo oludije rẹ, Oloye Oluṣọla Oke, ṣe gba lati ṣiṣẹ pọ pẹlu Gomina Rotimi Akeredolu lẹyin to fidi rẹmi ninu eto idibo abẹle ti wọn ṣe lọsẹ mẹta sẹyin.

Ọdun 2007 ni baba ti wọn n pe ni Jasper ọhun kẹyin si Oloogbe Olusẹgun Agagu to wa lori oye nigba naa, to si darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Labour, nibi ti Mimiko ti n dije.

Aarin oun ati gomina ana ọhun tun pada daru lọdun 2015 pẹlu bo ṣe kọ lati tẹle e pada sinu ẹgbẹ PDP, leyii to mu kawọn aṣofin ipinlẹ Ondo nigba naa yọ ọ nipo gẹgẹ bii igbakeji gomina.

Inu ẹgbẹ APC lo mori le lẹyin naa, o si wa lara awọn to ṣiṣẹ takuntakun lori bi Akeredolu ṣe jawe olubori ninu eto idibo ọdun 2016.

Akeredolu ti gba ijọba tan lọdun 2017 ki ile-ẹjọ too da baba naa lare, to si juwe ọna ti wọn fi yọ ọ nipo bii eyi ti ko bofin mu.

Ko sẹni to le sọ ni pato ohun to pada fa ija ajaku akata laarin awọn mejeeji, ohun tawọn kan n ṣakiyesi ni pe Alaaji ọhun wa lara awọn to n tako pupọ ninu awọn igbesẹ ti gomina n gbe. Ọlanusi gan-an ni wọn lo ṣaaju awọn oloye ẹgbẹ ti wọn da ẹgbẹ iṣọkan APC silẹ lọdun bii meji sẹyin.

Ohun ta a gbọ bayii ni pe, Ọnarebu Agboọla Ajayi ni ọkunrin naa fẹẹ ṣiṣẹ fun ninu eto ibo gomina to n bọ yii.

 

 

Leave a Reply