Nitori  ibo Ondo to n bọ, Akeredolu ṣabẹwo si Tinubu

Ibo ti won yoo di ni ipinlẹ Ondo lati yan gomina tuntun ko ju oṣu meji lọ bayii mọ, nigba naa ni Arakunrin Rotimi Akeredolu yoo gbejọba funra ẹ to ba jẹ oun lo wọle, tabi ko gbejọba fẹlomi-in to ba wọle. Laarin ẹgbe APC ati PDP ni kinni ọhun yoo ti le ju lọ. Ko ma di pe wọn ko kinni kan ku ninu ipalẹmọ ibo yii, Akeredolu ti ṣe abẹwo si Aṣiwaju ẹgbẹ APC, Bọla Ahmed Tinubu.

Ki i ṣe Tinubu nikan ni Gomina naa lọọ ri, o tun de ọdọ Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, naa. Akeredolu ṣalaye pe oun lọ si ọdọ Aṣiwaju APC yii ki oun le fi ẹni ti oun mu ni igbakeji oun han an ni, iyẹn Lucky Aiyedatiwa. Oun pẹlu ọkan ninu awọn eeyan Tinubu ni ipinlẹ Ondo, Ṣẹgun Abraham, ni wọn jọ lọ, Akeredolu si sọ ninu ọrọ to kọ jade sita pe oun nigbagbọ pe ti ko ba ti si iyapa kankan laaarin awọn, ẹgbẹ APC ni yoo bori ninu ibo naa.

Leave a Reply