Nitori ibo Satide, ijọba kede Furaidee gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ 

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, nijọba ti kede gẹ́gẹ́ bii ọjọ isinmi fawọn osisẹ ipinlẹ Ondo. Eyi ko sẹyin eto idibo ti yoo waye lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ ta a wa yii.

Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ondo, Donald Ọjọgo, lo fi atẹjade yii sita l’Ọjọbọ, Tọsidee.

O ni isinmi lẹnu iṣẹ yii yoo fun awọn oṣiṣẹ laaye lati rìn irin-ajo lọ si ibugbe olukuluku wọn, níbi ti wọn yoo ti lanfaani lati kopa ninu eto idibo naa.

O rọ gbogbo awọn osisẹ ọhun lati yago fun iwakiwa to ba ti ta ko ofin ati ilana ti ajọ eleto idibo ba fi lelẹ lasiko ti wọn ba jáde lati ṣe ojuṣe wọn. Bakan naa lo tun fi wọn lọkan balẹ pe ki wọn ma ṣe bẹru pẹlu awọn ẹṣọ alaabo to ti wa nikalẹ lati peṣe aabo fawọn oludibo lọjọ naa.

About admin

Check Also

2023: Ẹgbẹ TOTT rọ Tinubu atawọn oludije yooku lati panu pọ gbe Ọṣinbajo kalẹ

Ọrẹoluwa Adedeji Ẹgbẹ kan, The Ọsinbajo Think Tank (TOTT), ti parọwa si aṣaaju ẹgbẹ oṣelu …

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: