Nitori ibọn ti wọn yin ni Lẹkki: Wahala ba ijọba atawọn ọga ṣọja

Ademola Adejare

Bi ọrọ awọn olori ṣọja nilẹ wa ṣe n ṣe segesege lojoojumọ yii, ti ọpọlọpọ aṣiri si n tu, ti fẹẹ ṣe akoba fun awọn ọga ṣọja ati awọn ti wọn n ṣejọba ni Naijiria yii, ọrọ naa si ti ko wahala ba awọn eeyan naa, ere oriṣiiriṣii lawọn paapaa n sa kiri. Awọn ọmọwe kan lo kọkọ ko ara wọn jọ, wọn si le ni ọgọrin ti wọn ṣe bẹẹ, gbogbo wọn si pawọ-pọ, wọn kọwe si aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nilẹ Amẹrika, Joe Biden, wọn ni to ba ti gbajọba, ko ma fi oju aanu kankan wo ijọba orilẹ-ede Naijiria, ko ri i pe oun fiya to daa jẹ awọn ti wọn n ṣejọba yii, lori bi wọn ṣe yinbọn pa awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde ni Lẹkki. Awọn Purofẹsọ ati ọjọgbọn loriṣiiriṣii ni wọn para pọ kọwe naa, ti wọn si bẹ Joe Biden ati igbakeji ẹ, Kamala Harris, pe ki wọn fofin de gbogbo ẹni to ba lọwọ si ọrọ yii, paapaa awọn ti wọn n ṣejọba, pe wọn ko gbọdọ jẹ ki wọn wọ Amẹrika rara, awọn ati araale wọn.

Bi awọn ti kọwe yii, bẹẹ naa ni awọn orilẹ-ede ilẹ Yuroopu n mura, wọn fẹẹ wo ibi ti iwadii to n lọ lọwọ l’Ekoo yoo fi ori sọ, ki wọn too mọ ara ti wọn yoo da gan-an. Ṣugbọn ki i ṣe ara daadaa ni wọn fẹẹ da fawọn ti wọn n ṣejọba yii, wọn n wa ibi ti wọn yoo ti mu wọn pẹlu ofin to le koko ni, nitori ohun ti wọn ṣe fawọn ọdọ ni Lẹkki yii, ohun ti gbogbo aye lodi si ni, ti wọn si ni afi ki wọn ri i pe iru rẹ ko gbọdọ ṣẹlẹ nibi kankan lagbaaye mọ. Awọn ara United Kingdom tilẹ ti ṣaaju bayii, nitori lalẹ ana yii, ọrọ Naijiria ati awọn ṣọja ti wọn yinbọn yii ni wọn fi odidi wakati kan sọ nile-igbimọ aṣofin wọn, bi awọn kan si ti n pariwo pe ki wọn tete fiya jẹ Naijiria ati awọn ti wọn ba wa nidii ọrọ yii, awọn diẹ n bẹbẹ pe ki wọn jẹ ki awọn ti wọn n ṣe ijọba naa waa sọ tẹnu wọn.

Ohun to jẹ ki ọrọ yii le kari aye bayii ko ju bi ọrọ awọn ti wọn n ṣejọba ati awọn ṣọja ti wọn jade lọ sibi iṣẹlẹ yii ṣe n ṣe segesege lọ. Ohun kan tun ṣẹlẹ lọjọ Satide to kọja yii to mu kọrọ naa tun buru si i. Bẹẹ, ko too di ọjọ naa ni ileeṣẹ oniroyin agbaye, Cable News Network, iyẹn CNN, ti gbe iroyin jade nipa iṣẹlẹ naa, iroyin ọhun si kun fun iwadii ju eyi ti wọn ti n gbọ tẹlẹ lọ. Ninu iroyin naa lo ti han pe loootọ lawọn ṣọja yinbọn nibẹ, wọn ko si yinbọn soke gẹgẹ bi Ọga ṣọja, Ahmed Taiwo, ti wa siwaju igbimọ yii waa sọ. Ọga ṣọja yii ti sọ tẹlẹ niwaju igbimọ naa ni Satide to kọja lọ lọhun-un pe gbogbo awọn ṣọja ti wọn lọ sibi iṣẹlẹ naa, oke lasan ni wọn yinbọn si, ati pe ibọn ti wọn yin naa ko ni ọta ninu, ibọn adẹrubani lasan ni. Ṣugbọn nigba ti iroyin CNN yii jade, fidio fi awọn ṣọja ti ko yinbọn soke han, o si fi han gbangba pe ọta gidi wa ninu awọn ibọn naa.

Aṣiri ti CNN tun tu yii bi ijọba Naijiria ninu, minisita fun eto iroyin ijọba, Lai Muhammed, si jade pe awọn yoo fiya jẹ CNN, o ni gbogbo ọrọ ti wọn sọ yii, irọ lo wa nibẹ. Ṣugbọn awọn araaye gba CNN gbọ ju bẹẹ lọ. Wọn mọ pe iroyin ti awọn eeyan naa gbe ba jade, ootọ gidi ni. Yatọ si eyi, ohun ti wọn foju ri nibẹ ninu fidio ko ni irọ ninu nibi kan. Ohun ti Lai Muhammed n sọ ni pe ko si ẹni kankan to ku nibi iṣẹlẹ naa, pe CNN kan fẹẹ ba awọn lorukọ jẹ ni. Ṣugbọn bo ti n sọrọ tan, bẹẹ ni ileeṣẹ igbokuupamọ-si l’Ekoo kede pe ki awọn eeyan wa sọdọ wọn lati waa wo awọn oku to wa nibẹ, iyẹn awọn ti eeyan wọn ba sọnu laarin ọjọ kọkandinlogun, si ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, bẹẹ ogunjọ, oṣu yii, lawọn ṣọja ya bo wọn ni Lẹkki, ti oku si sun nibẹ daadaa. Itumọ eyi ni pe awọn oku kan wa ti wọn ku loootọ.

Yatọ si eyi, awọn eeyan kọọkan ti bẹrẹ si i jade lati sọ pe awọn n wa awọn eeyan awọn, awọn mi-in ti wọn si ti ri oku eeyan tiwọn, ti wọn mọ pe Lẹkki ni wọn ku si naa ti sọrọ, wọn royin iku to pa awọn eeyan wọn lasiko iwọde yii. Nidii eyi, ko si ibi ti ijọba yii fẹẹ sa si lori ọrọ yii mọ, o ti han pe ọpọ ọrọ to n jade ki i ṣe ootọ, ọrọ wọn n tase ara wọn. Bi nnkan si ṣe wa niyi nigba to tun di ọjọ Satide to kọja yii, nigba ti ọga ṣọja ni ọwọ kọkanlelọgọrin tawọn ologun (81 Division), nibi ti awọn ṣọja ti wọn yinbọn yii ti wa, jẹwọ pe ki oun sọ tootọ ki oun sọ tododo, awọn ṣọja ti wọn lọ si Lẹkki yii gbe ibọn dani, ati pe ninu awọn ibọn to wa lọwọ wọn, awọn ibọn kan wa to ni ọta ninu digbidigbi. O ni ko si bi awọn ṣọja yoo ṣe lọ si iru ibi iwọde bẹẹ ti wọn ko ni i gbe ibọn to lọta ninu dani, nitori awọn kan le fẹẹ kọ lu wọn nibẹ.

Nigba ti awọn agbẹjọro bẹrẹ si i fi ọrọ wa a lẹnu wo lori ohun to ti sọ tẹlẹ pe ibọn ti awọn ṣọja yin nibẹ ko lọta ninu lo ti tun pada jẹwọ pe awọn ibọn kan wa to lọta ninu o: Birigedia Ahmed Taiwo yii ni: “Dajudaju, awọn ṣọja ti wọn ba n lọ siru ibẹ yẹn, ninu wọn maa gbebọn to ni ọta ninu dani. Nitori boya awọn kan le fẹe kọ lu wọn ni. Ṣugbọn o, awọn ti wọn ṣaaju ti wọn yinbọn yẹn, ibọn ti ko lọta ninu lawọn n yin ni tiwọn!” Bayii ni Taiwo wi, ṣugbọn awọn eeyan ni o ṣoro pupọ lati gba ọrọ naa gbọ, nitori awọn ohun to ti kọja lọ tẹlẹ ti wọn gbọ, nigba ti awọn ṣọja yii ti kọkọ sọ pe awọn ko de Lẹkki, ti wọn tun sọ pe gomina lo ranṣẹ pe awọn, ti wọn si tun sọ pe awọn ko yinbọn, ki wọn too tun ni ibọn ti ko lọta ninu lawọn yin, ki wọn too tun waa sọ pe awọn ṣọja mi-in tun lọ sibẹ pẹlu ibọn to lọta ninu.

Nibi ti ọrọ waa de duro yii ni ọkan awọn ti wọn n ṣejọba Buhari yii ko balẹ, ohun to si n ja wọn laya ni pe ọrọ naa le buru ju bayii lọ. Bi ọrọ naa ba buru, to ba ṣe bayii dewaju ile-ẹjọ agbaye, ati awọn ọga ṣọja wọnyi, ati olori ijọba funra rẹ ni wọn yoo de ile-ẹjọ naa kawọ sẹyin, koda ko jẹ ọdun mẹwaa si ogun ọdun lo na wọn. Ohun ti awọn eeyan naa n sa fun ree, nitori wọn mọ pe igbẹyin ọrọ bẹẹ ko le dara. Nidii eyi, gbogbo ohun ti wọn le ṣe lati bo ọrọ naa mọlẹ ni wọn n ṣe, eyi lawọn eeyan ijọba si ṣe n tẹnu mọ ọn lojoojumọ pe ko sẹnikan to ku ni Lẹkki, ti wọn ni ẹni ti eeyan ẹ ba ku ni Lẹkki ko yọju sita. Amọ bi wọn ti n purọ naa, bẹẹ ni irọ ọhun n ja, awọn ti eeyan wọn ku n jade, awọn ti wọn tọju oku pamọ ni ki awọn eeyan waa wo awọn ti wọn ku boya eeyan wọn wa nibẹ, awọn ṣọja paapaa si ti jẹwọ pe loootọ lawọn lọ si Lẹkki pẹlu ibọn to lọta ninu.

Ijọba ipinlẹ Eko paapaa ko ti i wi kinni kan, ṣugbọn igbimọ to n ṣewadii ọrọ yii ti ni dandan ni Gomina Babajide Sanwo-Olu naa wa yọju sawọn, ko si waa sọ ohun to mọ nidii awọn ọrọ yii gan-an. Ṣe gomina naa lo kọkọ sọ pe awọn alagbara to ju oun lọ lo ko ṣọja jade, ki i ṣe oun, oun naa lo si sọ pe awọn oku meji ku nibẹ, bẹẹ lo sọ pe oun wa Buhari ti i ṣe olori ijọba titi, oun o ri i. Gbogbo ohun to sọ yii lo jẹ ki awọn ṣọja binu si i, ti wọn ni awọn ko ro iru ọrọ bẹẹ si i. Ohun ti awọn igbimọ yii ṣe ni afi ki oun naa maa bọ ree, wọn ni oriṣiiriṣii ọrọ to wa nilẹ yii lo da le e lori, bo ba si de ọdọ igbimọ, yoo le sọ gbogbo ohun to mọ sita. Ohun to daju ni pe bi Sanwo-Olu ba dewaju igbimọ yii, pẹrẹpẹrẹ mi-in yoo tun tu jade, nibi ti ọrọ naa yoo si fori sọlẹ si, ko sẹni to mọ. Eyi ni wahala to ba awọn to n ṣejọba l’Abuja, ati awọn ọga ṣọja, nitori ọrọ naa ti di ki olori dori ẹ mu o.

Leave a Reply