Nitori ifẹhonu han lodi si SARS, awọn ọdọ ba teṣan ọlọpaa jẹ n’Ijẹbu-Ode

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi ifẹhonu han ṣe n lọ kaakiri awọn ipinlẹ pe kijọba fagi le ikọ ọlọpaa adigboluja ti wọn n pe ni SARS, bẹẹ naa lo waye nipinlẹ Ogun, ṣugbọn janduku lawọn ọdọ to kopa ninu ẹ n’Ijẹbu-Ode fi tiwọn ṣe. Niṣe ni wọn wọ teṣan ọlọpaa Imoru lọ, ti wọn da ibẹ ru, ti wọn tun ji wọn lẹru lọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹwaa yii.

Ninu fidio kan to gun ori ayelujara lori rogbodiyan yii, awọn ọdọ kan ti wọn n fọ gilaasi oju ferese lo ṣafihan. Bi wọn ṣe n la igi mọ awọn ọkọ ti wọn paaki kalẹ ninu ọgba ọlọpaa naa ni wọn n fọ gilaasi ọkọ, bẹẹ ni wọn n ko awọn ohun tọwọ wọn ba nitosi lọ.

Ọkan ninu wọn wa ọkada to ba ninu ọgba ọlọpaa naa lọ, bẹẹ ni omi-in n tu taya mọto ti wọn paaki silẹ jẹẹjẹ.

Okuta nla atawọn nnkan ọṣẹ mi-in ni wọn tun n ju sinu ile lọdọ awọn ọlọpaa yii, bẹẹ ni wọn n ṣepe buruku fun wọn.

Bi wọn ti n ṣe eyi ni wọn n sọ pe ọlọpaa ti wọn ba bi daadaa ko jade sita waa koju awọn, wọn ni tọhun yoo jẹ buruku iya.

Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ ohun to fa a fi awọn ọdọ to n fẹhonu han nitori SARS naa ṣe tun sọ ọ di ohun ti wọn n ba nnkan jẹ ni teṣan bayii, kinni kan to daju ni pe iṣẹlẹ yii waye. Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun,  paapaa fidi ẹ mulẹ, o si binu gan-an si iwa ti awọn ọdọ naa hu.

Oyeyẹmi ṣalaye pe rogbodiyan to fa fifi opin si SARS ti wọn n beere kiri yii ko waye nipinlẹ Ogun, ki lo waa de to jẹ ipinlẹ ti ko mọ nipa ẹ lawọn eeyan yii doju ija kọ.

O ni awọn ti ṣeleri pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ lori eyi to ṣẹlẹ ni teṣan ọlọpaa yii yoo kabaamọ gidi.

O fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ti pe awọn ọba atawọn baalẹ pe ki wọn kilọ fawọn ọmọ ilu wọn, ki wọn ma ṣe lọwọ si iwọde onijagidijagan, nitori ẹni tọwọ ba tẹ nibi ifẹhonuhan to mu wahala dani ko ni i le royin tan.

Ọpọlọpọ eeyan lo fi aidunnu han si ohun ti awọn ọdọ wọnyi ṣe naa, wọn ni iwa arufin ni wọn hu, yoo si daa bawọn ọlọpaa ba ri mu ninu wọn lati fi wọn jofin.

 

Leave a Reply