Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Oyeniran Oyeyẹmi, ti sare pe ipade pajawiri latari ifẹhonu han tawọn kan n gbero lati ṣe lori ọrọ ọwọngogo epo bẹntiroolu ati owo Naira to n lọ lọwọ.
Ipade apero ọhun lo waye pẹlu awọn tọrọ kan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Akurẹ.
Ninu ọrọ to ba awọn to peju pesẹ sibi ipade naa sọ,
kọmiṣanna ọlọpaa ọhun ni iwadii awọn fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan kan tinu n bi ti n ko ara wọn jọ lati ṣewọde lori iṣẹlẹ to n lọ lọwọ nipinlẹ Ondo.
O waa lo asiko naa lati kilọ fun gbogbo awọn araalu pe awọn ọlọpaa ko ni i faaye gba iru iwọde bẹẹ lasiko yii, nitori o ṣee ṣe kawọn janduku kan ja iwọde ti wọn n gbero rẹ ọhun gba mọ wọn lọwọ, ki ohun gbogbo si di rudurudu.
Oyeyẹmi ni ṣe loun mọ-ọn–mọ pe awọn tọrọ kan sibi ipade naa ki wọn le waa ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ gan-an fawọn araalu ati ohun ti wọn ro pe yoo jẹ ọna abayọ.
Gbogbo awọn to wa nibi ipade naa ni wọn fẹnuko pe ki wọn yan awọn eeyan kan ti yoo maa mojuto awọn iṣẹlẹ to ba n waye kaakiri ipinlẹ Ondo ati ọna ti wọn yoo fi maa yanju rẹ nitubi inubi.
Lara awọn to wa nibi ipade ọhun ni ẹgbẹ awọn akẹkọọ, ẹka ti ipinlẹ Ondo, awọn alakooso ile-ifowopamọ, awọn alagbata epo bẹntiroolu atawọn mi-in.