Nitori igbakeji gomina, awọn aṣofin kọju ija sira wọn l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Wahala to n ṣẹlẹ nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo gbọna mi-in yọ laaarọ oni ti i ṣe Ọjọru,  Wẹsidee, pẹlu bi wọn ṣe jawe gbele-ẹ fun mẹta ninu awọn aṣofin to n ṣatilẹyin fun Igbakeji gomina, Ọnarebu Agboọla Ajayi, lori ẹsun afojudi ati ṣiṣe lodi sofin ile.

Awọn aṣofin tọrọ kan ni Ọnarebu Irọju Ogundeji, igbakeji abẹnugan to n ṣoju awọn eeyan Odigbo kin-in-ni, Adewale Williams Adewinlẹ to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo keji ati Abilekọ Tomomewo Shemmy Favour, aṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Ilajẹ keji.
Ọmọ ẹgbẹ APC lawọn aṣofin mẹtẹẹta, bẹẹ ni wọn wa lara awọn to kọwọ bọwe ta ko yiyọnipo Agboọla Ajayi lasiko ijokoo wọn to waye lọsẹ ta a wa yii.
Akọwe ile, Ọgbẹni Bọde Adeyẹlu, lo kọkọ dide lati ka iwe gbele-ẹ naa seti awọn ọmọ ile to wa ni ijokoo.
Lẹyin eyi ni Ọnọrebu Bamidele Ọlẹyẹlogun to jẹ abẹnugan ni àwọn ti n gbe igbesẹ ati ṣagbekalẹ igbimọ ti yoo ṣewadii lori ẹsun ti wọn fi kan awọn ọmọ tọrọ kan.
Gbogbo awọn to wa nile-igbimọ ọhun lo ba lojiji nigba ti Ọgbẹni Adeyẹlu tun  ka iwe ti aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Ariwa /Iwọ-Oorun Akoko, Ọnọrebu Suleiman Jamiu Maito, kọ pe oun kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii olori awọn ọmọ ile to pọ ju lọ.
Ṣe lawọn aṣofin naa doju ija kọ ara wọn ni kete ti wọn jade kuro ninu gbọngan ti wọn ti ṣepade.
Awọn ẹsọ alaabo to wa nitosi lo tete ba wọn da sọrọ naa ti wọn ko fi lu ara wọn.

Leave a Reply