Florence Babaṣọla
Ọmọkunrin kan ti wọn n pe ni Pepper ti ku latari bi awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe yinbọn fun un laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, lagbegbe Ita-Olookan, niluu Oṣogbo.
Ọkada meji la gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun gun lọ sibẹ, bi wọn si ṣe yinbọn fun Pepper tan ni wọn poora.
Iwadii fi han pe iwaju ile kan ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n lo lagbegbe naa ni wọn ka Pepper mọ ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ oni.
Nigba ti Pepper ri wọn, a gbọ pe o fẹẹ gbiyanju lati sa lọ, ṣugbọn awọn to fẹẹ pa a ti sun mọ ọn. Wọn yinbọn fun un lai mọye igba, nigba ti ko si mi mọ ni wọn too kuro nibẹ.
A gbọ pe ija agba lo waye laarin awọn ikọ ẹgbẹ okunkun meji, eleyii to si yọri si iku Pepper.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe wọn ti fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ awọn leti, koda, Kọmiṣanna ọlọpaa, Wale Ọlọkọde, ti ranṣẹ si DPO to wa lagbegbe naa.
O sọ pẹlu idaniloju pe laipẹ lọwọ yoo tẹ awọn to huwa naa.