Nitori ija agba laarin Imaamu ati aṣaaju ẹṣin, wọn ti mọṣalaaṣi pa n’Ikarẹ Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Irun Jimọh to yẹ ko waye ninu mọsalaasi gbogbogboo to wa niluu Ikarẹ Akoko ko ṣee ṣe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii pẹlu bi wọn ṣe ti ilẹkun mọsalaasi naa pa latari ija ajaku akata to n waye laarin Imaamu agba ile-ijọsin ọhun atawọn asaaju ẹṣin kan.

Akọroyin ALAROYE  fidi rẹ mulẹ pe ṣe lọrọ ọhun da bii idan loju pupọ awọn olujọsin naa nigba ti wọn de mọsalaasi lọsan-an ọjọ naa, ti wọn si ba geeti ibẹ ni titi pa gbọn-in gbọn-in.

Iwe alẹmogiri kan lawọn eeyan ba niwaju geeti naa, ninu eyi ti Olukarẹ tilu Ikarẹ Akoko, Ọba Saliu Akadiri, ti kilọ fun gbogbo awọn Musulumi lati rin jinna si mọsalaasi ọhun fungba diẹ na, titi ti rogbodiyan to n waye laarin ilu yoo fi rọlẹ.

Lati bii oṣu diẹ sẹyin la gbọ pe nnkan ti n gbona girigiri laarin awọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ mọṣalaasi ọhun, eyi ti Alaaji Jimọh Okeruwa jẹ alaga fun ati Imaamu agba tilu Ikarẹ, Sheiki Abass Abubakar.

Lara ohun to si n fa rukerudo ko sẹyin bi wọn ṣe ni Imaamu agba ọhun tu igbimọ majẹobajẹ naa ka, eyi ti ko fi bẹẹ dun mọ alaga atawọn ọmọ igbimọ naa ninu.

Ọrọ yii ni wọn lo ti fẹẹ maa mu wahala lọwọ diẹdiẹ laarin awọn alatilẹyin igun mejeeji, idi si ree ti Olukarẹ fi ti ilẹkun mọsalaasi naa pa lasiko to yẹ kawọn olujọsin waa kirun Jimọh lati dena rogbodiyan to le bẹ silẹ.

Bakan naa lawọn ẹṣọ alaabo tun n lọ, ti wọn n bọ, tawọn mi-in si duro wamuwamu si ayika mọṣalaasi ọhun lati ri i daju pe ko sẹni to huwa to le da omi alaafia ilu ru.

Leave a Reply