Nitori ija ilu Ẹrinle ati Ọffa, awọn alaṣẹ ti Poli Offa pa

Stephen Ajagbe, Ilorin

Latari ija to bẹ silẹ lori ọrọ aala ilẹ laarin ilu Ẹrinle, nijọba ibilẹ Ọyun, ati Ọffa, nijọba ibilẹ Ọffa, nipinlẹ Kwara, laarin ọsẹ yii, awọn alaṣẹ ileewe gbogboniṣe tijọba apapọ to paala laarin ilu mejeeji, Ọffa Poli, ti ti ileewe naa pa.

ALAROYE gbọ pe ileewe ọhun ti sare ko gbogbo awọn akẹkọọ to n gbe inu ọgba kuro lọ si olu ileewe naa to wa lọna Ilẹmọna fun aabo to peye.

Ṣe tipẹ lọrọ ala ilẹ ti n da wahala silẹ laarin ilu mejeeji. Koda, ohun tawọn araalu Ẹrinle n sọ ni pe ori ilẹ awọn gan-an nibi ti ileewe Poli Ọffa wa, ki i ṣe tilu Ọffa. Ọrọ naa ti wa nile-ẹjọ fun igba pipẹ.

Alukoro ileewe naa, Ọgbẹni Yinka Iroye, fidii iroyin yii mulẹ, o ni ileewe ọhun ni lati sare ko awọn akẹkọọ naa kuro lati le daabo bo wọn.

O ni awọn alaṣẹ ileewe yii ti ṣeto bi wọn yoo ṣe maa fun wọn lounjẹ, nitori pe ko si akẹkọọ kankan to raaye ko ẹru, to fi mọ ounjẹ wọn, lasiko ti ija naa bẹ silẹ.

Iroye ni pẹlu bawọn ṣọja ṣe wa kaakiri ilu Ọffa ati Ẹrinle, alaafia ti n pada sawọn ilu mejeeji.

O ṣalaye pe titi ileewe naa ṣe rẹgi pẹlu isinmi ọsẹ kan to maa n waye laarin saa ikẹkọọ, (Mid-semester break).

O ni lẹyin ọsẹ kan ileewe naa yoo di ṣiṣi.

Leave a Reply