Nitori ija oun ati Tinubu: Alaafin, Ọọni ṣepade pẹlu Arẹgbẹṣọla

Lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta yii, ni ALAROYE gbọ latẹnu awọn to mọ bo ṣe n lọ pe ipade pataki kan waye lati fopin si wahala to n ṣẹlẹ laarin Minisita feto abẹle, Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla, ati Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu.

Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi ati Ọọni Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi ni wọn ṣagbatẹru ipade ọhun ti wọn lo waye ni ile Alaafin Ọyọ kan to wa niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Ohun ti ipade ti wọn pe ni igbesẹ akọkọ naa da le lori ni bi gbọnmi-si-i-omi-o-to o to ti n ṣẹlẹ laarin ọga atọmọọsẹ yii, to fi mọ Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, yoo fi pari.

Odidi wakati meji lawọn ọba alaye yii pẹlu Arẹgbẹṣọla fi sọrọ. Lẹyin ajọsọ ọrọ ọhun ni wọn gba lati tun tẹsiwaju lati ri awọn tọrọ tun kan.

Leave a Reply