Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ajọ ẹṣọ oju popo, ẹka tilu Ọrẹ, ti kilọ fawọn awakọ lati sọra, ki wọn si yago fun ere asapajude nigbakuugba ti wọn ba ti wa lẹnu iṣẹ wọn nitori ijamba ọkọ to n waye lemọlemọ lagbegbe naa.
Ọga ẹsọ oju popo ẹka tilu Ọrẹ, Ọgbẹni Sikiru Alongẹ, lo parọwa yii lasiko to n fi ẹdun ọkan rẹ han lori ijamba ọkọ to fẹmi ọpọ eeyan ṣofo lagbegbe Ode-Aye, nijọba ibilẹ Okitipupa, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
Yatọ sawọn eeyan bii mẹwaa ti wọn pade iku ojiji lọjọ naa, marun-un ninu awọn arinrin-ajo ọhun lo ni wọn fara pa kọja bo ṣe yẹ, ti wọn si wa nileewosan ijọba ati ti aladaani kan l’Ọrẹ, nibi ti wọn ti n gba itọju.
O ni iṣẹ nla lapapọ awọn ẹsọ alaabo agbegbe Ọrẹ ati Okitipupa ṣe nibi ti wọn ti n gbiyanju lati ri awọn ọkọ to gbina naa pa nitori ki wọn le raaye yọ awọn to ha mọ inu ọkọ jade.
Gbogbo awọn olugbe awọn abule to wa lagbegbe iṣẹlẹ ohun lọkunrin naa ni awọn lọọ bẹ fun iranwọ ki wọn too ri ina to ṣẹ yọ lara awọn ọkọ naa pa patapata.
Alongẹ ni ohun tawọn ṣakiyesi ni pe, awakọ Coaster ati ti J5 naa fori sọ ara wọn latari ere asaju ti wọn n sa níbi ti wọn ti n gbiyanju ati pẹwọ fawọn koto keekeeke to wa loju ọna ni.
Ọga awọn ẹsọ oju popo ọhun rọ awọn awakọ lati kọ bi wọn ṣe n mu suuru nigbakuigba ti wọn ba ti wa lẹnu isẹ wọn.