Nitori ijinigbe: Awọn ọlọkada ipinlẹ Ogun yoo bẹrẹ si i wọṣọ idanimọ

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Pẹlu bi eto aabo ṣe mẹhẹ gidi lorilẹ-ede yii, to si jẹ pe awọn oniṣẹ ibi n lo ọkada nigba mi-in lati huwa laabi wọn, ijọba ipinlẹ Ogun ti pinnu lati bẹrẹ eto iforukọsilẹ fawọn ọlọkada ilu naa bayii, wọn yoo si tun maa wọ aṣọ idanimọ ti yoo fi wọn han bii ojulowo ọlọkada gidi.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un, ni Kọmiṣanna fun eto irinna nipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Gbenga Dairo, sọ eyi di mimọ lẹyin ipade awọn alẹnulọrọ ti wọn fi wakati mẹta ṣe nile igbafẹ awọn ọlọpaa, l’Abẹokuta.

Ninu ipade to kan TRACE, FRSC, ẹgbẹ ọlọkada ati onimaruwa; ACOMORAN, ROMO, AMORAN, awọn fijilante So-Safe, Imigireṣan atawọn ọtẹlẹmuyẹ DSS ni wọn ti fẹnu ko pe ijọba ipinlẹ Ogun yoo maa mojuto iṣẹ awọn ọlọkada bayii.

Wọn ni wọn yoo bẹrẹ iforukọsilẹ fun wọn, wọn yoo mojuto nọmba to wa lara ọkada kọọkan, ijọba yoo maa fun wọn ni iwe aṣẹ ti wọn fi le kọja laduugbo kan (permit). Paripari ẹ ni ti aṣọ iṣẹ idanimọ ti wọn yoo maa wọ, eyi ti wọn ti ṣe ami idanimọ si lara.

Nipa bi gbogbo awọn nnkan wọnyi yoo ṣe jẹ ṣiṣe, kọmiṣanna eto irinna nipinlẹ yii ṣalaye pe awọn olori yuniọnu kọọkan ni yoo mu un lọkun-un-kundun lati ri i pe eto naa bẹrẹ kia nipa pipese orukọ awọn ọlọkada to n ṣiṣẹ labẹ wọn.

Awọn orukọ yii ni ijọba yoo fi ṣe akọsilẹ iye ọlọkada to n rin loju popo, ti wọn yoo si fi akọsilẹ orukọ wọn sinu kọmputa ijọba.

Ninu ọrọ tiẹ, Alaga ACOMORAN nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Kayọde Amos Showumi, ni awọn yuniọnu ti gba ohun ti ijọba n fẹ lati ṣẹgun iwa ọdaran yii wọle. Bẹẹ lo fi da wọn loju pe iforukọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ yoo bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ, gbogbo ipa lawọn yoo si sa lati ri i pe awọn ran ijọba yii lọwọ.

Showumi kilọ fawọn ọlọkada pe ki wọn joye oju lalakan fi n ṣọri bi wọn ba n ṣiṣẹ oojọ wọn lọwọ. O ni ki wọn kọyin si iwa ọdaran, ere asapajude,ki wọn si maa tẹle idari ina atọnisọna loju popo.

O ni ọmọ ẹgbẹ yoowu tọwọ ba tẹ nibi to ti n huwa to lodi sofin yoo gba pe ofin ko mọ ọba, bẹẹ ni ko mọ ijoye.

Leave a Reply