Nitori ijinigbe, ijọba Ogun fẹẹ gba awọn ẹṣọ alaabo sawọn ileewe ijọba

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Pẹlu bo ṣe jẹ pe ijinigbe ti n ṣẹlẹ lawọn ileewe lawọn ipinlẹ Naijiria kan, ijọba ipinlẹ Ogun ti Gomina Ọmọọba Dapọ Abiọdun n ṣakoso ẹ, ti bẹrẹ igbesẹ lati gba awọn ẹṣọ alaabo ti yoo maa ṣọ ileewe ijọba lawọn ipinlẹ yii.

Gomina Abiọdun lo sọ eyi di mimọ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹta, yii l’Abẹokuta, nigba ti awọn ọga lẹka ẹkọ alakọọbẹrẹ nipinlẹ yii, ṣabẹwo si i lọfiisi rẹ.

Abiọdun sọ pe, ‘’Gẹgẹ bi ijọba to mọ ohun to tọ, mo ti fọwọ si gbigba awọn ẹṣọ alaabo sawọn ileewe wa. A o fẹẹ maa sare kiri ti wahala ba ṣẹlẹ, ko ma ṣẹlẹ rara la ṣe n tete mojuto o. Bẹẹ la fẹẹ ri i daju pe ki i ṣe awọn akẹkọọ nikan ni aabo wa fun, bakan naa lawọn tiṣa gbọdọ ni aabo to peye’’

 

Nigba to n sọrọ lori aaye tawọn ọmọ ti n kẹkọọ lawọn ileewe ijọba nipinlẹ yii, Abiọdun sọ pe ko bojumu rara ni. O ni bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ ẹ lawọn ti tunṣe, sibẹ, eyi to nilo atunṣe ṣi pọ, ṣugbọn ki saa iṣakoso yii too pari, Abiọdun ni ẹgbẹta (600) ileewe, o kere tan, loun yoo ti tunṣe.

O fi kun un pe iṣẹ agbaṣe wa fun ẹgbẹrun lọna ọgọta ( 60,000) aga ijokoo tijọba fẹẹ pese fawọn ileewe, kawọn ọmọ le ri nnkan jokoo kọwe bo ṣe yẹ.

Alaga igbimọ ẹkọ alakọọbẹrẹ to ṣabẹwo si gomina, Ọjọgbọn Ihonvbere, dupẹ lọwọ Gomina Abiọdun fun bo ṣe san owo to yẹ fawọn lọdun 2018, 2019 ati 2020.

O fi kun un pe kekere kọ lohun toju awọn ileewe alakọọbẹrẹ n ri lasiko yii lawọn ipinlẹ, o ni kijọba Ogun ma kaaarẹ lori ipese aabo, ki wọn ṣe fẹnsi sawọn ileewe, ki wọn ṣe omi sibẹ ki wọn si tun awọn eyi to ti dẹnukọlẹ ṣe.

Leave a Reply