Nitori ijinigbe ojoojumọ, awọn ẹṣọ alaabo fẹẹ ya wọ igbo Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Pẹlu bi awọn ajinigbe ṣe fẹẹ maa fojoojumọ ṣọṣẹ, ijọba ipinlẹ Ekiti ti ṣeto ipade apero kan fun gbogbo awọn ẹṣọ alaabo to wa nipinlẹ naa, ki apero le waye ṣaaju igbesẹ kikoju awọn oniṣẹ laabi ọhun.

Nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii Gomina Kayọde Fayẹmi ṣide eto Exercise Crocodile Smile VI ti yoo ran awọn ẹṣọ alaabo lọwọ lati koju ipenija eto aabo, paapaa pẹlu bi ipari ọdun ṣe de.

Fayẹmi, ẹni ti Oludamọran pataki lori eto aabo, Ọgagun-fẹyinti Ebenezer Ogundana, ṣoju fun sọ pe ni kete ti ipejọpọ naa ba wa sopin lawọn ẹṣọ alaabo yoo ya wọ gbogbo ibu ati ooro Ekiti lati gbena woju awọn ọdaran, ati lati dena iṣẹlẹ ijinigbe atawọn iwa to jọ mọ ọn.

Gomina naa ni ipade yii yoo fun awọn olori ikọ ẹṣọ alaabo kọọkan lanfaani lati ṣagbekalẹ eto aabo ti yoo koju ijinigbe, idigunjale ati ifẹmiṣofo, ati pe igbesẹ to kan ni lati ko awọn eeyan naa lọ sawọn ibi tawọn ọdaran ti n ṣọṣẹ.

Fayẹmi ni, ‘A mọ bi eto aabo ilẹ Naijiria ṣe ri lọwọlọwọ, lara ẹ si ni nnkan to n ṣẹlẹ l’Ekiti. Awọn ta a ko jọ sibi lonii mọ awọn igbesẹ ti wọn yoo gbe, ti ipade yii ba si ti pari, a jẹ pe gbogbo wa la le lọ sile lati sun, ka si pa oju mejeeji de.

‘Idi ta a tun fi ko wọn jọ ni pe a ko fẹ ki awọn ṣọja maa ṣe tiwọn, ki ọlọpaa naa maa ṣe tiwọn, iyẹn la ṣe ko gbogbo ẹ papọ ta a pe e ni Exercise Crocodile Smile VI. Lati asiko yii lọ, awọn eeyan maa ri i pe Ekiti ti yatọ nilana eto aabo.’

Leave a Reply