Nitori ijinigbe to n waye lemọlemọ, wọn fẹẹ f’Oro ṣọde l’Ọbada-Oko

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Nigba to ti han gedegbe pe ko si aabo mọ, ti ijinigbe ti di nnkan gbogbo igba l’Ọbada-Oko, iyẹn nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, awọn eeyan agbegbe naa ti panu-pọ lati fi Oro ṣọde lati kapa awọn ajinigbe to n fi wọn jẹun naa.

Gẹgẹ bi atẹjade to ti ọwọ Alaga agbegbe Aso Rock, Ijẹja-Ojurin CDA, Ọbada Oko, wa, iyẹn Ọnimọ-ẹrọ Sanni Ọladimeji, o ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii, ni Oro yoo jade l’Ọbada Oko, lati aago meje alẹ mọju aarọ ọjọ keji.

Atẹjade naa rọ awọn araalu pe ki ẹni to gbọ tete sọ fawọn ti ko ba ti i gbọ, pe Oro yoo gbode, ko saaye irin ko sọbẹ nilẹ to ba ti n di aago meje alẹ, titi ti ilẹ ọjọ keji ti i ṣe Furaidee yoo fi mọ.

Latari Oro ti wọn fẹẹ gbe jade yii, oriṣiiriṣii ero ọkan lawọn eeyan ti fi sita, bawọn kan ṣe n sọ pe ijọba ti ko le pese aabo faraalu lo fa a, lawọn mi-in sọ pe bo ti le wu ki aabo ma si to, Oro kọ lo yẹ ki wọn fi ṣọde.

Awọn ti ko fara mọ aba naa sọ pe gbigbe Oro jade lasiko naa tumọ si titẹ ẹtọ araalu lati rin nigba to wu wọn loju, eyi si le fa idiwọ fun ọpọ eeyan to ṣee ṣe ki wọn ma ti i dari de lati ibi iṣẹ wọn lasiko ti isede naa fẹẹ bẹrẹ.

Wọn fi kun un pe ibi ti wọn ti fẹẹ sede yii tilẹ le ma jẹ apa ibi ti awọn ajinigbe wa rara, ti isede naa ko si ni i tu iru kan lara wọn.

Ṣugbọn awọn mi-in sọ pe lilo Oro lati sede ki i ṣe ere rara, wọn ni iṣẹ Oro ki i ṣe iṣẹ ọjọ kan, wọn yoo maa jẹ anfaani rẹ lọ fungba pipẹ ni, nitori wọn yoo lo asiko ti Oro ba fi gbode naa lati ṣe awọn nnkan ti yoo daabo bo ilu karikari fun igba pipẹ ni. Wọn ni to ba ru ni loju, aa bi ilẹ leere lawọn agba wi.

Ṣe yatọ si ijinigbe bii meloo kan to ti waye l’Ọbada tẹlẹ, ọjọ Satide to kọja yii ni awọn ajinigbe tun ji awọn mẹta kan gbe, ti wọn n beere miliọnu mẹwaa naira, oogun oloro Codeine tijọba ti fofin de ati ounjẹ ki wọn too le fi awọn ti wọn gbe lọ naa silẹ.

Ẹnikan to kọ lati darukọ ẹ ninu awọn araalu naa sọ fawọn akọroyin lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ji awọn eeyan naa gbe pe awọn ti san miliọnu kan aabọ fawọn ajinigbe naa, awọn fi oogun oloro ti wọn fẹ naa si i pẹlu, bẹẹ lawọn ko ounjẹ fawọn ajinigbe ọhun pẹlu omi, nigba naa ni wọn si fi awọn eeyan ti wọn ji gbe naa silẹ.

Leave a Reply