Nitori ikọlu awọn ajinigbe, ijọba ipinlẹ Ondo ti gbe ibudo awọn ologun lọ si Ọ̀ṣẹ́

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ijọba ipinlẹ Ondo ti paṣẹ gbigbe ibudo awọn ọmọ ologun lọ sijọba ibilẹ Ọsẹ, lati le fopin si iṣẹlẹ ijinigbe gbogbo igba to n waye lagbegbe naa.

Alakooso Amọtẹkun ipinlẹ Ondo, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ, to tun jẹ olubadamọran fun gomina lori eto aabo lo fidi eyi mulẹ fáwọn oniroyin kan lọfiisi rẹ to wa ni Alagbaka, Akurẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ta a wa yii.

Adelẹyẹ nijọba ti pinnu ati kọ ibudo ọhun siluu Imoru, nijọba ibilẹ Ọsẹ, nibi ti awọn ọmọ ologun, ọlọ́pàá, sifu difẹnsi, ọlọpaa inu atawọn Amọtẹkun yoo fi ṣe ibudo ti wọn yoo ti maa peṣe aabo fawọn eeyan to n gbe ni gbogbo agbegbe naa.

O ni ijọba gbe igbeṣẹ yii lati le raaye dojukọ ọkan-o-jọkan ipenija eto aabo to n waye lagbegbe Ọsẹ ki awon eeyan ibẹ si le sun asunwọra paapaa lasiko ọdún Ileya to n bọ lọna lọsẹ yii.

Adelẹyẹ ni ohun ti awọn ṣakiyesi ni pe oju omi làwọn ọdaran to n ṣiṣẹ ibi lagbegbe naa n gba wa nigbakugba ti wọn ba ti fẹẹ pa itu ọwọ wọn, o ni idi ree ti ijọba fi yan ilu Imoru laayo lati kọ ibudo ọhun si ki ọwọ-ija awọn ẹsọ alaabo naa baa le de gbogbo ibi tawọn oniṣẹẹbi ọhun ba n gba ṣọṣẹ.

Ọga awọn ẹsọ Amọtẹkun ọhun waa kilọ fun gbogbo awọn ọba atawọn ijoye ilu ki wọn jawọ ninu tita tabi fi fun awon ajinigbe atawọn darandaran nilẹ nitori ìjọba ti paṣẹ fún wọn láti maa forukọ silẹ na saaju ki wọn too le gbe nibikibi nipinlẹ Ondo.

O ni ìjọba ti paṣẹ fáwọn ologun pẹlu awọn ẹsọ afarajologun ki wọn bẹ̀rẹ̀ sii mojuto awọn aala ipinlẹ Ondo to wa lagbegbe Akoko, Kogi ati Edo latari àwọn ajinigbe to ti sọ awọn agbegbe naa di ibuba wọn.

Awọn òṣìṣẹ́ ẹsọ Amọtẹkun to to bii ẹgbẹrun meji lo ni awọn ti da si igboro lati peṣe aabo fáwọn araalu ni gbogbo àwọn ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa ni ipinlẹ Ondo lasiko ọdun Ileya yii bẹ̀rẹ̀ lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ́ kejidinlọgbọn oṣù kẹfà titi di ọjọ Aje, Mọnde ọjọ́ kẹta oṣù keje ọdún 2023.

Akọgun Adelẹyẹ ni iranlọwọ ti àwọn n beere fun lọdọ àwọn araalu ni ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹsọ alaabo ki wọn si tete maa fi ohunkóhun to ba n ṣẹlẹ̀ ni ayika wọn to awon leti nipa pipe nọmba foonu yii: 08079999989.

 

Leave a Reply