Iku Odumain: Awọn agbaagba Yoruba ṣabẹwo ibanikẹdun si Baba Adebanjọ

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn eeyan nla nla nilẹ Yoruba ṣi n wọ lọ si ile Olori awọn Afẹnifẹre, Pa Ayọ Adesanya, lati ba a daro ọkan pataki ninu awọn ọmọ Yoruba to ku lojiji lọjọ Abamẹta, Satide,  Yinka Odumakin.

Ẹmọ ku oju opo di, aferemojo ku, isa n ṣọfọ lọrọ iku ojiji to gbẹmin gbajugbaja akọroyin ati Alukoro ẹgbẹ Afẹnifẹre nni, Oloye Yinka Odumakin.

Owurọ kutu ọjọ Abamẹta, Satide yii, la gbọ pe alukoro ẹgbẹ Afẹnifẹre yii doloogbe lẹyin aisan ranpẹ kan to ni i ṣe pẹlu arun Korona. Ẹka ti wọn ti n tọju awọn to lugbadi arun Koronafairọọsi lọkunrin naa ku si nileewosan  Fasiti ipinlẹ Eko (Lagos State University Teaching Hospital, LASUTH) to wa n’Ikẹja.

Atẹjade kan ti Abilekọ Odumakin fi lede lori iṣẹlẹ ọhun sọ pe ibi ti wọn ti n tọju awọn taisan wọn legbakan lọsibitu ọhun ni Yinka Odumakin dakẹ si, o lo ti kọkọ lugbadi arun Koro tẹlẹ, ṣugbọn o ti gbadun ko too di pe nnkan tun yiwọ ni nnkan bii ọsẹ kan sẹyin.

Wọn lawọn mọlẹbi maa kede ọjọ isinku laipẹ.

Akọroyin to dantọ ni Yinka Odumakin, o si jẹ ọkan pataki ninu awọn alẹnulọrọ ilẹ Yoruba, paapaa lori ọrọ oṣelu ilẹ wa, ati bi ilẹ Yoruba yoo ṣe lalaafia, ti igbe aye irọrun yoo si wa fawọn eeyan agbegbe naa.

Aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, atawọn eeyan nla nla mi-in lo ti n ṣedaro akọni ọmọ Yoruba yii.

Leave a Reply