Nitori ina to jo o, ijọba ni kawọn onimọto yẹra fun biriiji ọna Airport lasiko yii

Faith Adebọla, Eko

Ijọba ti kilọ pe ki awọn onimọto yẹra fun gbigba biriiji to lọ lati Ibudokọ Toyota si ọna papakọ ofurufu Muritala Mohammed, kọja lasiko yii, wọn nijọba fẹẹ ṣayewo lati mọ ipo ti biriiji naa wa latari ina nla to jo o lọsẹ to kọja.

Ọga agba nileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si ọna ati iṣẹ ode, Ọgbẹni Olukayọde Popoọla, lo ṣekilọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, pe kawọn onimọto ṣi ni suuru kijọba fi ṣayẹwo si afara ọhun, ki wọn le mọ boya o ṣi lagbara, to si fi ni lọkan balẹ fawọn ọkọ lati rin lori ẹ.

O ni o ṣe ni laaanu pe awọn alaibikita ẹda kan maa n wọ awọn nnkan ti wọn fi di ọna ati gun biriiji naa kuro, paapaa lọwọ alẹ, ti wọn yoo si kọja lọ ni tiwọn, pe iru iwa bẹẹ lewu gidi.

Popoọla ni ọṣẹ ti ijamba ina to waye labẹ biriiji naa ṣe ki i ṣe kekere rara, awọn si ti bu ilẹ afara naa dani lọ fun ayẹwo lati mọ boya ina naa ti sọ biriiji ọhun di ẹbiti iku tabi bẹẹ kọ, ati boya atunṣe ṣi le wa si awọn nnkan ti ina buruku ọhun bajẹ.

Tori bẹẹ, ọkunrin naa ni ijọba ko ni i fẹ kawọn eeyan fẹmi ara wọn wewu nipa lilo biriiji ọhun.

O tun fi kun un pe ina naa ti ba iṣẹ kọnkere ẹgbẹ titi Oshodi si Apapa to n lọ lọwọ jẹ, o si ti sami sawọn opo kan to gbe biriiji ọhun duro.

Tẹ o ba gbagbe, Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, ni ina nla kan bu yọ lagbegbe naa latari bi ọkọ tanka ti epo bẹntiroolu kun inu rẹ ṣe ṣubu, to si gbina loju ọna Apapa si Oṣodi, ina ọhun si ṣan de gbogbo agbegbe naa.

Leave a Reply