Nitori ipenija eto aabo, awọn alaṣẹ Poli Ibadan dawọ awọn iṣẹ to n lọ ninu ọgba naa duro

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi nnkan ko ṣe ṣenuure lori ọrọ aabo nileewe Gbogbonise, Ibadan (The Polytechnic, Ibadan) awọn alaṣẹ ileewe naa ti dawọ iṣẹ duro.

Ninu atẹjade ti Akọwe-agba ileewe ọhun, Modupẹ Fawale, fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan lọjọ Aiku, Sannde, kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun yii, ni wọn ti kede eyi faye gbọ.

Igbesẹ ọhun ni wọn lo waye lati le dena ofo ẹmi ati dukia awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ poli naa latari ikọlu awọn ọmọ iṣọta to maa n waye lagbegbe ileewe naa nigba gbogbo lẹnu lọọlọọ yii.

Bakan naa ni wọn lawọn alaṣẹ ileewe yii paṣẹ idawọ iṣẹ duro lati le dena itankalẹ kokoro arun Korona.

Ninu ọrọ tiẹ, Alukoro ileewe naa, Alhaji Adewọle Sọladoye, sọ pe bi ọkan ko ṣe balẹ mọ nipa bi ọrọ eto aabo ṣe n mi lẹsẹ ninu ọgba ileewe naa lo nilo ayẹwo ati apero to peye, ki wọn le mọ ibi to yẹ lati gbọrọ naa gba.

Amọ ṣa, wọn ni idaduro iṣẹ to waye lojiji yii ko ni i ṣediwọ fun idanwo saa keji to n lọ lọwọ.

Wọn ti waa rọ awọn igbimọ apẹtusaawọ, awọn adari ẹka ẹkọ, awọn aṣoju ẹgbẹ awọn akẹkọọ atawọn ẹgbẹ to jẹ mọ ẹsin gbogbo ninu ọgba ile-ẹkọ naa lati tẹle alakalẹ ofin ati ilana ti awọn alaṣẹ ileewe naa fi lelẹ lati dena laasigbo ati itankalẹ kokoro arun Korona nileewe naa.

 

Leave a Reply