Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti ti fun alaga ijọba ibilẹ Ikẹrẹ, Ọnarebu Fẹmi Ayọdele, niwee gbele-ẹ lẹyin ọjọ diẹ to polongo atilẹyin fun iyansipo Gomina Kayọde Fayẹmi gẹgẹ bii aarẹ ilẹ yii lọdun 2020.
Ayọdele lo gbe igbesẹ naa pẹlu awọn iwe ipolongo to gbe sori intanẹẹti, eyi to ti da wahala silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ ati lagbo oṣelu kaakiri ilẹ yii.
Ṣaaju loun funra ẹ ti sọ pe oun ṣe ipolongo naa lati fi atilẹyin han fun Fayẹmi, ẹni tawọn kan ro pe oun ko fẹran, ati pe ootọ inu loun fi ṣe e. Ṣugbọn latigba tọrọ naa ti di wahala lo ti dakẹ, ko si ba ẹnikẹni sọrọ lori rogbodiyan ọhun mọ.
Bakan naa ni Fayẹmi kede pe oun ko mọ nnkan kan nipa igbesẹ ọhun, bẹẹ ni inu oun ko dun si i nitori o da nnkan toun ko reti silẹ. O ni ọrọ idagbasoke Ekiti lo jẹ oun logun lasiko yii, ki i ṣe ibo 2023.
Lonii ni ile igbimọ aṣofin labẹ idari abẹnugan wọn, Ọnarebu Funminiyi Afuyẹ, sọ pe ki Ayọdele lọọ sinmi nile titi ti iwadii yoo fi pari lori iwa to hu, eyi to lodi sọfin.
Olori ọmọ ile to pọ ju, Ọnarebu Gboyega Aribiṣogan, lo gbe aba naa kalẹ, bẹẹ ni Ọnarebu Tajudeen Akingbolu kin in lẹyin, bẹẹ lawọn mi-in sọ pe abuku gbaa ni nnkan ti alaga ọhun ṣe jẹ fun Fayẹmi.
Ile naa waa gbe iṣẹ iwadii ijinlẹ fun igbimọ to n ri si ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, wọn yoo si jabọ laarin ọsẹ kan.