Nitori ireke aadọta Naira, Hausa gun Yoruba lọbẹ n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ṣe ni ibẹrubojo gbilẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni ọja kan to gbajugbaja niluu Ilọrin ti wọn n pe ni Mandete, lakooko ti rogbodiyan bẹ silẹ nigba ti Hausa to n ta ireke gun Yoruba kan lọbẹ nitori ireke aadọta Naira.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe ajọ naa gba ipe pajawiri ni owurọ kutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, pe ẹya Yoruba ati Hausa ti fija pẹẹta ni ọja Mandete, ọpẹlọpẹ ajọ naa to ka awọn eniyan ọja ọhun lọwọ ko, nnkan o ba bajẹ ju bo ṣe yẹ lọ.

O tẹsiwaju pe arakunrin Yoruba kan lo ra ireke aadọta naira lọwọ Hausa, lo ba sọ pe ko dun, ko paarọ ireke naa, eyi ni wọn lo da edeiyede silẹ laarin wọn ti Hausa si gun Yoruba lọbẹ, ni ẹjẹ ba n ṣan bii omi. Eyi lo pada di ija ẹlẹyamẹya. Yoruba ati Hausa ba kọju ija si ara wọn. Wọn si ti gbe ọkunrin ti wọn gun lọbẹ lọ si ileewosan fun itọju to peye.

Adari ajọ ṣifu difẹnsi, Ọgbẹni Makinde Ayinla, ti waa paṣẹ pe ki awọn ẹsọ alaabo duro wamuwamu fun odidi wakati mẹrindinlogun ni gbogbo agbegbe ọja ọhun lati dena rogbodiyan ọtun.

Leave a Reply