Nitori irẹsi idaji apo, awọn aṣọbode yinbọn pa Tunde ni Yewa, wọn nijọba apapọ ti ni kawọn maa pa ẹni tawọn ba ri ẹru ofin lọwọ rẹ 

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Tunde Alabe ni wọn pe orukọ ẹ, gende to ṣi niyaa ati baba laye ni. O niyawo pẹlu, ṣugbọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2021, ododo arẹwa ọkunrin yii rẹ danu, wọn ni awọn kọsitọọmu yinbọn pa a l’Ebute Igbo-Ọrọ, nitosi Ilaro, nipinlẹ Ogun, lasiko ti wọn ni wọn ba idaji apo irẹsi lọwọ ọdọ kan.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an gẹgẹ bi aṣofin to n ṣoju ẹkun Yewa keji nile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnarebu Wahab Egungbohun, ṣe wi ni pe ki i ṣe Tunde nikan ni wọn pa o. O ni awọn ọdọ mi-in naa tun wa ti wọn ba iṣẹlẹ yii rin, ohun to si fa a ko ju pe wọn ni ẹnikan ninu wọn ni idaji apo irẹsi ilẹ okeere lọwọ, ni wọn ba kọju ibọn si wọn.

Egungbohun sọ pe, ‘‘Tunde lọọ ra epo bẹntiroolu ni fun jẹnẹretọ ẹ ni,  jẹẹjẹ ẹ lo n bọ ki wọn too yinbọn pa a.

‘’Wọn lawọn kan gbe idaji apo irẹsi lọwọ ni wọn tori ẹ bẹrẹ si i yinbọn. Ohun tawọn kọsitọọmu yẹn sọ ni pe ijọba apapọ ti sọ pe kawọn maa pa ẹni tawọn ba ba ri ẹru ofin lọwọ ẹ. Ṣugbọn ti wọn ba n yinbọn fẹni to ni irẹsi lọwọ, kin ni wọn waa fẹẹ ṣe fẹni to gbe ibọn AK 47 dani.

‘‘Awọn Fulani lo n gbe ibọn kiri yẹn, wọn ko ti i ri ẹni kan ṣoṣo mu ninu wọn pẹlu gbogbo  nnkan to n ṣẹlẹ yii, wọn o dẹ yinbọn pa wọn.

‘‘Wọn ko wọnu ilu lati gba awọn ti Fulani n da laamu silẹ, ṣugbọn apapọ awọn kọsitọọmu, ṣọja ati imigireṣan yii le wọnu igbo lati maa wa onifayawọ kiri. Ẹnikẹni ti wọn ba ti ri, wọn maa yinbọn fun un ni. ‘‘Kinni yii ti n ri bẹẹ tipẹ ti ijọba dakẹ lori ẹ, ti wọn ko ṣe nnkan kan si i. Gbogbo awọn to n ṣe fayawọ yii naa kọ ni ko kawe, awọn to kawe jade nileewe giga wa ninu wọn, airiṣẹ ṣe lo jẹ ki wọn maa ṣe fayawọ kiri. Ẹyin tẹ ẹ le lọọ kogun ba onifayawọ ninu igbo, ẹ maa gbọ pe Fulani n paayan laarin ilu, ẹ o ni i lọ sibẹ. O baayan lọkan jẹ pupọ’’’

Ibi kan ti wọn n pe ni Ọlajogun, ni wọn ti yinbọn pa ibẹ lawọn aṣọbode naa ti yinbọn mọ ẹni ti ko mọwọ mẹsẹ, to jẹ ile-epo lo ti n bọ jẹẹjẹ rẹ lai ba ẹnikẹni fa wahala kankan gẹgẹ bi Ọnarebu Wahab ṣe wi.

Nigba to n sọrọ nipa iye eeyan to ku ninu ikọlu awọn Fulani to waye ni Orile-Igboro lọjọ Ẹti to kọja yii, Ọnarebu yii sọ pe eeyan mẹta lawọn ti ri oku wọn lọjọ Satide ti i ṣe ọjọ keji iṣẹlẹ naa.

O ni awọn mẹjọ wa nileewosan nitori ada tawọn Fulani ṣa wọn. Awọn olori ilẹ kan naa wa to ni awọn ko ri, ibomi-in si wa to jẹ ọkọ ni wọn yoo ri, ti iyawo ti ba rogbodiyan Fulani naa lọ.

O ni wọn dana sunle, wọn ba dukia ọpọ eeyan jẹ, wọn si ṣe bẹẹ tan, wọn na papa bora.

Ọjọ ti ai le sun dọkan yii yoo dopin nipinlẹ Ogun, paapaa nilẹ Yewa, lawọn eeyan ibẹ n reti. Wọn ni bawọn ṣe n padanu ẹmi sọwọ kọsitọọmu lawọn Fulani naa n ṣe tiwọn, bẹẹ, ko jọ pe olugbeja kan wa nitosi lasiko yii, nitori awọn ko ri ọwọ ijọba lasiko iṣoro awọn.

Leave a Reply