Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Amofin Fẹmi Emmanuel Emadamori ti wọ ajọ eleto idibo lorilẹ-ede yii lọ sile-ẹjọ fun bi wọn ṣe kọ lati fi awọn iwe-ẹri ti Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo,. Ọnarebu Agboọla Ajayi, sita.
Ọsẹ to kọja ni agba amofin ọhun kọkọ kọwe kan si ajọ naa, ninu eyi to ti loun fun wọn lọjọ meje pere lati fi awọn iwe-ẹri ọkunrin naa sita.
Emadamori ni oun fẹẹ ri awọn iwe-ẹri Ajayi ti oludije sipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu ZLP ko fun ajọ naa nitori pe oun fura pe ayederu ni gbogbo ohun to ko fun wọn.
O ni ṣe lọkunrin naa kan sọ fun ajọ eleto idibo pe iwe mẹwaa loun ni, o si kuna lati ṣafihan iwe-ẹri to darukọ naa fun aridaju.
Agbẹjọro ọhun ni ki adajọ pasẹ fun ajọ naa lati tẹ awọn iwe-ẹri ti igbakeji gomina ko fun wọn sita fun awọn eeyan lati ri ni ibamu pẹlu ila kẹta ninu abala kọkanlelọgbọn iwe ofin eto idibo ọdun 2010.