Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC), ninu eto idibo gomina ipinlẹ Ondo to n bọ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, Ọgbẹni Kunle Wiseman Ajayi, atawọn mẹjọ mi-in lawọn ọlọpaa fi pampẹ ofin gbe nibi ti wọn pejọ pọ si lati kopa ninu aṣekagba iwọde ‘ẹ fi opin si ijọba buruku’, eyi ti wọn fẹẹ ṣe n’iluu Akurẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
Ẹgbẹ oṣelu African Action Congress lo jẹ ẹgbẹ Ọmọyẹle Ṣoworẹ, to jẹ ọkan pataki ninu awọn to ṣe agbatẹru ifẹhonu ‘ẹ fi opin si ijọba buruku’ eyi ti wọn bẹrẹ rẹ lọjọ kin-in-ni, oṣu yii.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ọdọ awọn ti wọn wa nitosi lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye pe bi awọn oluwọde ọhun ṣe n ko ara wọn jọ si agbegbe NEPA, niluu Akurẹ, lọjọ yii lawọn ọlọpaa kan ya bo wọn, ti wọn si fẹẹ fi tipatipa tu wọn ka.
Agbẹjọro ajafẹtọọ ọmọniyan kan toun naa wa nibi iṣẹlẹ yii, Amofin Tọpẹ Tèmókún, ni ko si wahala, bẹẹ ni ko si ọna kankan ti awọn oluwọde naa fi ṣẹ sofin, eyi tawọn ọlọpaa le tori rẹ waa fi pampẹ gbe ẹnikẹni.
Tèmókún ni iwa ika patapata gbaa lawọn ẹṣọ alaabo hu ọhun pẹlu bi wọn ṣe waa ya bo awọn laijẹ pe awọn n fa wahala tabi da ilu ru lasiko ti awọn fẹẹ bẹrẹ ifẹhonu han lọjọ naa.
O ni lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ, iyẹn lọjọ to ku ọjọ to ku ọla ti awọn fẹẹ ṣe iwọde ni awọn ọmọ ẹgbẹ ‘Gba a pada’ ti kọ lẹta si awọn ọlọpaa lati fi to wọn leti, ti awọn si bẹbẹ fun idaabobo awọn lasiko iwọde naa.
O ni bi awọn ṣe ko ara awọn jọ si agbegbe NEPA, pẹlu ọkan-o-jọkan ìwé ifẹhonuhan ti awọn kọ akọle si ni awọn ọga ọlọpaa kan waa ba awọn sọrọ, ti wọn si rọ awọn lati maa lọ si papa Arcade, to wa lẹgbẹẹ ileegbimọ aṣofin to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, nibi to yẹ ki ifẹhonuhan ọjọ naa ti waye.
Amofin Tèmókún ni loju-ẹsẹ ẹsẹ lawọn ti gbọran si awọn ọlọpaa lẹnu pẹlu bi awọn ṣe to lọwọọwọ lati maa lọ si gbagede Arcade, ti wọn ni ki awọn maa lọ, lai mọ pe ṣe ni wọn kan fẹẹ fi ọgbọn alumọkọrọyi tan awọn kuro ni ojutaye, ki wọn le raaye ṣe ifẹ inu wọn fun awọn.
O ni bi awọn ṣe rin siwaju diẹ lawọn ọlọpaa ti wọn ti sapamọ sibi kan deedee yọ lojiji, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe mẹsan-an ninu awọn olufẹhonu han naa pẹlu awawi pe lati oke ni aṣẹ ti wa lati ṣe bẹẹ.
O ni gbogbo ọna ni awọn fi ta ko ọna ẹtan tawọn ọlọpaa fi ko awọn to n ṣe iwọde jẹẹjẹ wọn, ati pe ti awọn agbofinro ba ni ohunkohun gẹgẹ bii ẹri pe ifẹhonu han naa mu jagidijagan lọwọ, awọn n reti ki wọn yara tete ko o jade.
Gbogbo akitiyan wa lati ri Alukoro Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ba sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun ko so eeso rere pẹlu bo ṣe ni oun wa nibi iṣẹ pataki kan lasiko naa.
Ọsẹ to kọja ni Ṣoworẹ kọkọ fi atẹjade kan sita lori ikanni Fesibuuku rẹ, ninu eyi to ti ni ọpọn iwọde to n lọ lọwọ yoo sun kan ipinlẹ Ondo lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ karun-un, oṣu yii.
Ṣoworẹ ni oun rọ gbogbo awọn ọdọ ati awọn to n poungbẹ fun eto ijọba rere lati tu yaayaa jade, ki wọn si ko ara wọn jọ si agbegbe NEPA, n’iluu Akurẹ, nibi ti iwọde naa yoo ti gbera sọ.
Yatọ si awọn ọlọpaa ti wọn ti pin ara wọn kaakiri ilu Akurẹ ṣaaju ọjọ ta a n sọrọ rẹ yii, bi ilẹ ọjọ Aje, Mọnnde, ọhun ṣe n mọ lawọn tọọgi kan ti ko ara wọn jọ, ti awọn naa si duro kaakiri awọn agbegbe kan niluu Akurẹ, pẹlu atoori lọwọ wọn, eyi ti wọn fẹẹ fi ṣọkọ fun ẹnikẹni to ba dabaa lati jade waa fẹhonu han.
Boya ibẹru ikọlu lati ọdọ awọn ẹlẹkẹru yii ni ko jẹ kawọn to n gbero ati fẹhonu han tun yọju sita mọ.
Kete ti iroyin yii ti jade lawọn eeyan kan ti n sọrọ, ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ tawọn agbofinro gbe ọhun.
Alaga fun ẹgbẹ awọn aṣoju-kọroyin nipinlẹ Ondo (Correspondents’ Chapel), Ọgbẹni Tosin Ajuwọn, lo kọkọ ta ko igbesẹ yii ninu atẹjade kan to fi soju opo Fesibuuku rẹ.
Ajuwọn ni iwa titẹ ẹtọ ọmọniyan loju lawọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo hu pẹlu bi wọn ṣe lọọ ko awọn ẹni ẹlẹni nibi ti wọn ti n ṣe iwọde alaafia nitori ebi buruku to n pa araalu.
O ni ki i ṣohun to bojumu rara pẹlu bi awọn ọlọpaa adigboluja ṣe n dira ogun lọọ ṣe ikọlu si awọn olufẹhonu han ti wọn ko mu nnkan ija lọwọ, ti wọn si ṣe bẹẹ fi pampẹ ofin gbe Kunle Wiseman Ajayi, Patric Owolabi, Kọlawọle Kumuyi, Oluwatobi Akinkuotu, Ọlalekan Ọladehinde atawọn mi-in.
O ni ko dara ki ijọba kan loun fẹẹ maa gbogun ti awọn alatako rẹ ti wọn n ja fitafita lori bi ilu yoo ṣe dara nitori ko ṣẹni ti ko mọ pe asiko yii ko dẹrun rara fawọn mẹkunnu, nigba tawọn oloṣelu n jaye ọlọba ni tiwọn lai ni imọlara iya to n jẹ awọn eeyan.
Alaga awọn aṣoju-kọroyin ọhun ni o ṣe ni laaanu pe agidi nijọba to wa lode ko bori dipo ki wọn gbọ igbe ẹdun tawọn araalu n ke, kí wọn si tete wa nnkan ṣe lori inira ti ọwọngogo ounjẹ, epo bẹntiroolu mu ba awọn eeyan.
O ni oun n rọ kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abayọmi Ọladipọ, lati bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan, ko si tete tu gbogbo awọn oluwọde ti wọn fi pampẹ ofin gbe silẹ lẹyẹ-o-sọka.
Ṣoworẹ naa ko gbẹyin ninu awọn to fi ibinu sọko ọrọ si awọn ọlọpaa ati Gomina Lucky Ayedatiwa lori iṣẹlẹ ta a n sọrọ rẹ yii. O fẹsun kan Gomina Ayedatiwa pe ṣe lo kowo fawọn tọọgi kan lati ṣe ikọlu si awọn to n ṣe iwọde alaafia. O ni oun mọ pe bi awọn ọlọpaa tun ṣe lọọ mu Kunle Ajayi atawọn mi-in l’Akurẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu yii, ko sẹyin rẹ bakan naa.
O ni ohun ti Ayedatiwa gbagbe ni pe awọn to n dẹ awọn ọlọpaa si bii aja yii ni wọn ja fun un lati de ipo gomina to wa lonii, nipasẹ eto kan ti awọn gbe kalẹ nigba naa, eyi ti awọn pe ni ‘Aketi gbọdọ lọ’
O waa rọ awọn ọlọpaa ki wọn tete fi gbogbo awọn ti wọn ti mọle lori iwọde alaafia ti wọn n se silẹ ti ko ba fẹẹ gba alejo awọn nipinlẹ Ondo laipẹ.
Oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party ninu eto idibo to n bọ, Ọgbẹni Bamidele Akingboye, naa tabuku awọn agbofinro lori fifi pampẹ ofin gbe awọn oluwọde naa.
O waa rọ Gomina Ayedatiwa ko yara wa gbogbo ọna ti yoo fi yọnda awọn ajafẹtọọ ọhun, nitori oun mọ pe igbesẹ bi wọn ṣe fi pampẹ ofin gbe wọn ko sẹyin rẹ rara.