Nitori iwọde SARS, ọmọ Ibo gbe awọn olorin, oṣere atawọn mi-in lọ sile-ẹjọ

Jide Alabi

Eeyan bii aadọta l’ọkunrin ọmọ Ibo kan, Kenechukwu Okeke, to pe ara ẹ ni ajafẹtọọ ọmọ eniyan ti gbe lọ sile-ẹjọ lori ẹsun pe awọn ni wọn gbe owo kalẹ fi ṣatilẹyin fawọn to ṣewọde ta ko ẹṣọ agbofinro SARS.
Lara awọn eeyan to pe lẹjọ ni Aisha Yesufu, Yẹmi Alade, Innocent Idibia, Pasitọ Sam Adeyemi atawọn marundinlaaadọta mi-in. O lawọn eeyan wọnyi lọwọ si iwọde ọhun daadaa, oun sì fẹẹ ba wọn ṣẹjọ ni.

Ile ẹjọ gíga kan niluu Abuja lo pe ẹjọ ọhun sí, nibi to ti fẹsun kan awọn olorin, awọn gbajumọ kan laarin ilu, agbabọọlu atawọn mi-in yii.
Ẹsun ti Okeke fi kan awọn eeyan ọhun ni pe wọn gbìmọ-pọ, wọn ṣatilẹyin fun awọn to ṣewọde lati fi di alaafia ilu lọwọ pẹlu ero pe awọn n ta ko ifiyajẹni ti awọn ẹṣọ agbofinro SARS n ṣe fun araalu ni. O ni ipejọ wọn ọhun waye laarin ọjọ keji si ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii.
O ni iwa ti wọn n hu yii ni ijiya labẹ ofin ọdun 2004.
Ọkunrin yii fi kun un pe ikojọpọ wọn ati iwọde ti wọn ṣe paapaa niluu Abuja ko ṣai ṣakoba fun oun lori bi wọn ṣe ba dukia oun jẹ nigba ti ikojọpọ wọn pada di rogbodiyan, ti ọpọ dukia si ṣofo danu.
Gbogbo awọn eeyan bii aadọta to ko orukọ wọn jọ naa lo ni oun fẹẹ ba ṣẹjọ nitori awọn gan-an ni wọn ṣokunfa bi awọn janduku ṣe ba oun ni dukia jẹ.

Lara awọn olorin, awọn gbajumọ oṣere, onitiata atawọn mi-in laarin ilu to pe lẹjọ wọnyi ni:
David Adeleke (Davido), Fọlarin Falana (Falz), Debọ Adedayọ (Mr Macaroni) Maryam Akpaokagi.
Awọn mi-in tun ni Peter ati Paul Okoye, Bankọle Wellington (Banky W), Tiwa Savage, Michael Ajereh (Don Jazzy); agbabọọlu nni, Kanu Nwankwo; akọroyin kan, Kiki Mordi, Yul Edochie, Uche Jombo, Feyikẹmi Abudu, Ọlọrunrinu Oduala, Pamilẹrin Adegoke, Japhet Ọmọjuwa, Ayọ Ṣogunro, Deji Adeyanju atawọn mi-in.

Leave a Reply